Ọmoͅ osͅù méͅfà kú lórí èͅsùn pè ìyá rèͅ fun ní òògùn olóró ‘Tramadol’

Aworan

Iroyin lati orileͅede Cameroon fi lede pe arabinrin kan ti gbeͅmi oͅmoͅ reͅ leͅyin to fun ni oogun oloro Tramadol ko le sun foͅnfoͅn.

Awoͅn aradugbo ti oͅroͅ naa sͅoju woͅn ni o dabi eͅni pe ara ikoko naa ko ya, ti o si n jeͅrora ni eͅgbeͅ kan, amoͅ nise ni iya reͅ ti ilekun moͅ to si sͅI faanu tii lasiko to feͅ loͅ jaye ni ile igbafeͅ (Clubhouse).

Woͅn ni nigba to de aaroͅ oͅjoͅ keji lo ri pe oͅmoͅ naa ko mi moͅ, to fi gbe jade.

Aibikita iya lo pa oͅmoͅ naa…

Agbegbe Quarter 9, Likomba, Tiko Sub-division ni eͅkun iwoͅ oorun Cameroon ni isͅeͅleͅ naa ti waye.

Bi awoͅn ara adugbo sͅe gboͅ oͅroͅ yii ni woͅn beͅreͅ si ni na obinrin to fun oͅmoͅ reͅ ni oogun oloro Tramadol mu naa.

‘’Kii se igba akoͅkoͅ niyii ti Ngodere, iya oͅmoͅ naa yoo ma fun oͅmoͅ reͅ ni Tramadol, ki o ba le rin irin tireͅ jade kuro ni ile.’’

‘’Aibikita iya lo pa oͅmoͅ naa, ti awoͅn miran si ni o yin oͅmoͅ naa ni oͅrun pa ni,amoͅ o ni oͅroͅ ko ri beͅeͅ.

Fidio to n ja ranyin nita safihan bi woͅn se n na arabinrin naa, ti oͅpoͅ ero si pejoͅ si beͅ, peͅlu oͅmoͅ ikoko naa loͅwoͅ ti ko mi moͅ.

Eͅgbon Ngodere ti woͅn feͅsun kan pe o fun oͅmoͅ reͅ ni Tramadol oͅhun lo loͅ fi eͅjoͅ reͅ sun ni ileͅjoͅ amoͅ ti woͅn ni woͅn ko fi panpeͅ mu nitori oͅroͅ abeͅle ni.

Leͅyin naa ni woͅn ni woͅn gbe loͅ si sͅoͅoͅsͅI fun adura.

Ki isͅeͅleͅ yii to waye ni iya reͅ ni Ngodere ti sa kuro nile nitori o gba oyun.

Kini oogun Tramadol?

Gͅeͅgeͅ bi awoͅn onimoͅ sͅe soͅ, oogun Tramadol ni woͅn ma n lo fun awoͅn eniyan ni ileewosan ti woͅn ba n jeͅ irora, ti ko si ni jeͅ eͅni oͅun ni imoͅlara irora to n la koͅja.

O seese ki awoͅn eniyan sͅI oogun yii lo tabi ki o di baraku, ti o si lee jasi iku.

Ni awoͅn orileͅede ni Africa, oogun Tramadol peͅlu awoͅn oogun ti woͅn fofin de pe woͅn ko gboͅdoͅ maa taa lai gba iwe asͅeͅ lati ileewosan.

Amoͅ oͅpoͅloͅpoͅ awoͅn oͅdoͅ ni woͅn n sͅI oogun yii lo lai bikita ipalara to n sͅe fun ara woͅn.

Agbeͅnusoͅ fun eͅkun ti isͅelͅeͅ naa ti waye ni woͅn ma n ta oogun oloro naa ni agbegbe Tiko, ti eͅnikeͅni si lee na oͅwoͅ si lati raa.