Olùwọ́de 47 nínú àwọn tí ọlọ́pàá kó ní ìwọ́de Yoruba Nation ti gba ìtúsílẹ̀ láhámọ́ ọlọ́pàá

Yoruba nation

Mẹtadinlaadọta ninu awọn oluwọde mejidinlaadọta ti ọlọpaa mu lasiko iwọde Yoruba Nation to waye lọjọ kẹta oṣu keje ọdun 2021 ti kuro ni ahamọ awọn ọlọpaa bayii lẹyin ti wọn ti mu awọn gbedeke beeli wọn ṣẹ.

Alukoro ẹgbẹ ilana ọmọ Oodua, Maxwell Adelẹyẹ lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to fi sita lalẹ ọjọ Iṣẹgun.

Àwọn olùwọ́de 48 Yoruba Nation dèrò ilé-ẹjọ́ tórí a ká ìbọn àti àkéé mọ́ wọn lọ́wọ́- Ọlọ́pàá

Ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ idi ti o fi gbe awọn oluwọde Yoruba nation mejidinlaadọta lọ si ile ẹjọ.

Nigba ti o ba BBC Yoruba sọrọ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, CSP Muyiwa Adejobi ṣalaye pe oriṣiiriṣii ohun ija bii ibọn ati aake ni ọlọpaa ka mọ wọn lọwọ.

Arọ ọjọ Aje lawọn mejulaadọta foju ba ile ẹjọ Majisireeti niluu Eko lori oriṣiiriṣii ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

CSP Adejobi ni ara ẹsun ti ọlọpaa fi kan wọn ni igbiyanju lati daluru ati kiko ibọn lọwọ lai laṣẹ .

”Koda awọn mii ti a ka ibọn mọ wọn lọwọ sa kuro ninu ọkọ wọn ti wọn si fẹsẹ fẹẹ.

Awọn ẹsun mii ti wọn fi kan awọn eeyan naa ni pipe jọ ni ọna to tapa si ofin ati iwa to le ṣakoba fun alaafia ilu.

Ẹwẹ, atẹjade kan ti ẹgbẹ Ilana Omo oodua fi sita lati ọwọ alukoro ẹgbẹ naa, Maxwell Adeleye sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti fẹsun kan ọkan lara awọn oluwọde 48 naa, Ọgbẹni Tajudeen Bakare(Olori Ogboni) pe oun ni afurasi to ṣeku pa Jumoke Oyeleke to n ta omi inu ọra(pure water).

Amọṣa, CSP Adejobi ni oun ko le sọ ohun kan lori ọrọ Olori Ogboni nitori oun ko tii ka iwe ipẹjọ naa daadaa.

Ọjọ kẹta oṣu keje ni awọn eeyan naa ṣe iwọde fun idasilẹ orilẹede Yoruba legbegbe Ojota niluu Eko.

Nibi iwọde yii naa ni awọn ọlọpaa ti fi ọwọ ofin mu wọn ki ọrọ naa to de ile ẹjọ.