Olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ ajaguntà Wagner Group, Yevgeny Prigozhin jáde láyé

Yevgeny Prigozhin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọga agba ileeṣẹ ajagunta Wagner group, Yevgeny Prigozhin, ti jade laye.

Iku ọkunrin naa lo waye lẹyin ti ọkọ ofurufu to wa ninu ja lulẹ.

Iṣẹlẹ yii lo n waye lẹyin oṣu meji to gbiyanju lati gba ijọba lọwọ Aarẹ orilẹ-ede Russia, Vladmire Putin.

Ninu fidio kan to ti n milẹ titi lori ayelujara bayii, a ri ọkọ ofurufu naa bo ṣe gbina loju ofurufu, to si ja lulẹ lagbegbe Bologovsky.

Awọn onwoye gbagbọ pe o ṣeeṣe ki ọkunrin naa ma si ninu ọkọ ofurufu ọhun lasiko to ja lulẹ.

Amọ ileeṣẹ iroyin Daily Mail ilẹ Gẹẹsi jabọ pe ileeṣẹ to n ri si irinna ọkọ ofurufu ni Russia, Rosaviatsiya, sọ pe ologbe naa wa lara awọn ero ọkọ ofurufu naa lasiko to ja lulẹ.

Iroyin ni o kere tan, eeyan mẹsan an lo wa ninu ọkọ ofurufu ọhun lasiko ti ijamba naa waye.

Oṣe yii lo pe oṣu meji gerege ti oloogbe naa gbiyanjuu lati ditẹ gbajọba lọwọ Aarẹ Putin.

Ti ẹ ko ba gbagbe, awọn ọmọ ẹgbẹ ajagunta ọkunrin naa n ṣatilẹyin fun awọn ologun to ditẹgbajọba lorilẹ-ede Niger, eyii to ti da rogbodiyan silẹ ni iha iwọ oorun Afrika.