Ọlọ́pàá kan d’àwátì l’Ogun, ẹbí rẹ̀ fẹ́ gbé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lọ sílé ẹjọ́

Ọlọpaa PC Emmanuel Gene

Oríṣun àwòrán, Other

Lẹyin oṣu mẹsan ti ọlọpaa kan, Emmanuel Gene to n ṣiṣẹ lapa Ijebu Igbo nipinlẹ Ogun ti di awati, ẹbi rẹ ti ni awọn ṣetan lati gbe ileeṣẹ ọlọpaa lọ si ile ẹjọ.

Agbẹjọro ẹbi Gene, Kehinde Bamiwola Esq fi iwe ipẹjọ ranṣẹ si alaga ajọ PSC to n ri si ọrọ awọn ọlọpaa ati ọga agba ọlọpaa to fi mọ ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun.

Awọn ẹbi ọlọpaa naa n beere pe ki ileeṣẹ ọlọpaa wa ọmọkunrin naa ri bo ya o wa laaye ni tabi o ti ku.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọpọ eeyan lo ro pe awọn janduku ji Gene gbe lọ nibi tawọn ọlọpaa ti ṣiṣẹ kan ni Aba Tuntun loṣu kejila ọdun 2020.

O ti to bi ọdun kan bayii ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ eleyii ti ẹbi rẹ ko gbọ ohun kan.

Koda, ohun ti a gbọ ni pe iyawo ọlọpaa naa ti bimọ bayii.

Awọn ẹbi Gene ti kepe ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, alakoso iṣẹ ọlọpaa lagbegbe Ijebu Ode ati DPO ọfiisi ti Gene ti n ṣiṣẹ lati wa nkan ṣe si ọrọ to wa nlẹ yii.

Agbẹjọro Bamiwola Esq iyalẹnu lo jẹ pe DPO Ijebu Igbo, S.P Kazeem Solatan sọ pe awọn gbalẹ-gbalẹ lo ji Gene gbe lọ ni ilu Aba Tuntun.

Ṣugbọn Bamiwola ni ohun to jẹ kayeefi ni pe ileeṣẹ ọlọpaa ri bata, baagi ati ibọn Gene.

”Bawo ni wọn ṣe maa ji i gbe ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ri awọn nkan rẹ yii ti wọn ko si ri oun gan an fun ra rẹ?

O jẹ iyalẹnu pe DPO ko le sọ pato ohun to ṣẹlẹ si Gene gan an.

O ti fẹ pe ọdun kan bayii ti ileeṣẹ ọlọpaa ko si ri Gene doola to ba jẹ pe lootọọ ni wọn jigbe e.

A n duro de esi ileeṣẹ ọlọpaa lori oun to ṣẹlẹ si ọlọpaa Gene to di awati gan an,” Bamiwola lo sọ bẹẹ.

Ẹwẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbola Oyeyemi ṣalaye fun BBC Yoruba pe iṣẹ lawọn ọlọpaa naa lọ sẹ ni Aba Tuntun.

DSP Oyeyemi ni ko si ẹni to ran awọn ọlọpaa lọ sibi ti wọn ti n ja ija ilẹ, awọn kan ti wọn ni wọn gbe ohun ija oloro wọ agbegbe Ije Igbo lawọn ọlọpaa lọ fun.

”DPO gan an fun ra rẹ lo ṣaaju awọn ọlọpaaa lọ si ibi iṣẹ yii, wọn si fọwọ ṣinkun ofin mu gbogbo awọn to gbe oun ija oloro naa wọ ilu.

Nigba ti wọn n bọ lawọn kan lọ fawọn lọna, wọn si ji ọlọpaa mẹrin lọ pẹlu Gene, koda DPO gan an farapa nibi iṣẹlẹ ọhun.

Ileeṣẹ ọlọpaa ri mẹta ninu mẹrin awọn ọlọpaa ti wọn jigbe yii doola ṣugbọn.

Ṣugbọn ohun to ṣẹlẹ ni pe Gene to di awati yii ti sa kuro nibi tawọn mẹta yoku ti wọn ri doala naa duro si.

Ni bayii, ileeṣẹ ọlọpaa ti mu marun un lara awọn to ṣiṣẹ ibi yii.

Ko si ọrọ ninu ohun ti ẹbi Gene n sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ja ọrọ naa kunra rara,” DSP Oyeyemi ṣalaye