Ọlọ́pàá fọhùn pé ẹgbẹ́ IPOB ni àwọn agbébọn tú ẹlẹ́wọ̀n 1,844 sílẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Owerri

Ọgba Ẹwọn Owerri

Ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ to n ja fun idasilẹ orilẹ-ede Biafra (IPOB), ati ikọ alaabo ni ẹkun Ila oorun, ESN, lo ṣe ikọlu si ọgba ẹwọn nilu Owerri lọjọ Aje.

Ọga Agba ọlọpaa, Mohammed Adamu sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ IPOB ati ESN to ṣe ikọlu naa pọ , to si jẹ pe awsn nkan ijagun igbalode ati abugbamu ni wọn ko lọ si ibi iṣẹlẹ naa.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Frank Mba fi sita ni Mohammed ti sọ pe “igbiyanju awọn agbebọn naa lati wọ ibi ti awọn ọlọpaa n ko awọn nkan ijagun si ni olu ileeṣẹ ọlọpaa lo ja si ofo, nitpri pe awọn ọlọpaa to wa lẹnu iṣẹ ko gba fun wọn”.

O ni digbi ni ibudo naa wa, ti ko si si ọlọpaa kankan to ku sinu iṣẹlẹ naa yatọ si kọnstebu ọlọpaa kan ti ọta ibọn ba ni ejika.

Amọ ninu iroyin mii, adele Ọga Agba ni ajọ to n mojuto ọgba ẹwọn ni Naijiria, ẹka ti ipinlẹ Imo, John Mrabure sọ pe ẹlẹwọn 1,844, ni awọn agbebọn naa tu silẹ.

Agbẹnusọ ajọ ọgba ẹwọn to jẹ ti ijọba apapọ, Francis Enobere, to fi atẹjade naa sita sọ pe “ni nkan bi aago meji oru ọjọ Aje, ọjọ karun-un, oṣu Kẹrin, ọdun 2021, ni awọn agbebọn naa wọ inu ọgba naa, ti wọn si fi nkan abugbamu fs awọn ọfiisi to wa nibẹ.

Building dem attack

Iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii sọ pe eeyan kan ti dero ọrun lẹyin ti awọn agbebọn kọlu ọgba ẹwọn kan niluu Oweri, nipinlẹ Imo.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, iṣẹlẹ naa waye lorumọju, ko si ṣeni to tii le sọ boya ẹlẹwọn kankan ti salọ.

Awọn fidio kan to wa loju opo ikansiraẹni lori ayelujara ṣafihan bi iro ibọn ṣe n dun kẹukẹu.

Owerri prison

A ko tii le sọ ni pato awọn to wa nidii akọlu naa, gbogbo akitiyan wa lati kan si ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ọhun lo ja si pabo.

Ẹwẹ, akọroyin BBC to wa ni ilu naa lọwọ yii jabọ pe wọn ti yibọn pa ẹlẹwọn kan lasiko to n gbiyanju lati salọ.

A ṣi n ṣe akojọpọ iroyin yii lọwọ, a oo maa fi to yin leti bo ba ṣe n lọ.

Owerri prison
Building wey dem attack