Ọlọ́pàá yìnbọn lu Adájọ́ lásìkò ìgbẹ́jọ́

Aworan aṣọ Ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọga ọlọpaa kan sina bọlẹ fun Adajọ ileẹjọ magistrate ni olu ilu Kenya, Nairobi.

Iṣẹlẹ naa lo jẹ ohun iyalẹnu fun ọpọ araalu lorilẹede naa.

Ohun to tẹ wa lọwọ ni BBC ni pe, Ọga ọlọpaa ti orukọ n jẹ Kipchirchir Kipruto binu nitori ile ẹjọ kọ lati gba baali iyawo rẹ .

Ko pẹ si igba to gbe idajọ kalẹ ni Ọlọpaa yii yinbọn lu Adajọ Monica Kovuti pe ran iyawo rẹ lọ si ẹwọn fun ẹsun ti ile ẹjọ ri pe o jẹ bi.

Ọga ọlọpaa naa to jẹ olori fun ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Londiani ni iwọ oorun orilẹede naa yọ ibọn naa sita lati apo rẹ, to si yin lu Adajọ, ẹni to si farapa.

Kete bi iṣẹlẹ naa waye ni ija bẹ silẹ ni ile ẹjọ, ti ọkan lara awọn ọlọpaa si ṣekupa Kiprutu.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni mẹta ninu awọn ọlọpaa to koju Kiprutu lo farapa ninu iṣẹlẹ naa.

Adajọ atawọn mẹta to farapa nibi iṣẹlẹ naa ti wa ni ile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju.