Ọkùnrin kan dáná sun ìyàwó rẹ̀ dójú ikú l’Ogun

Iná tó ń jó ènìyàn

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Arákùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ponle Adebanjo ti dáná sun ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí níná nítorí tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́, Lateefat kọ Ponle sílẹ̀ nítorí pé Ponle máa ń lù ú ní gbogbo ìgbà tí wọ́n fi wà pọ̀.

Ọdún mẹ́ta ni àwọn méjéèjì fi gbé pọ̀ gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya ní agbègbè Otun-Akute kí Lateefat tó pinu láti kúrò ní ilé Ponle nígbà tí ara rẹ̀ kò gbà lílù tí ọkọ rẹ̀ máa ń lù ú mọ́.

Lẹ́yìn ìgbà náà ni Lateefat lọ dá gba ilé sí òpópónà kan náà tí òun àti ọkọ rẹ̀ jọ ń gbé ṣùgbọ́n tí Ponle túnbọ̀ máa ń ṣọ kiri.

Ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ni Ponle gba ilé tí Lateefat ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà tó ti ń dá gbé lọ ní agbègbè Otun-Akute ní ìpínlẹ̀ Ogun tó sì dáná sun-ún.

Nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹta, oṣù Keje agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Abimbola Oyeyemi ní àwọn tọkọtaya náà ti di olóògbé báyìí.

Oyeyemi ṣàlàyé pé Lateefat ti bí ọmọ mẹ́rin nínú ìgbéyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ kó tó pàdé Ponle.

Ó ní ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ni àgọ́ ọlọ́pàá tó wà ní Otun-Akute nawọ́ gán Ponle lẹ́yìn tí àwọn ara ilé Lateefat lọ fi ẹjọ́ ọkùnrin náà sùn.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ní àwọn ará ilé Lateefat fẹ̀sùn kàn wí pé Ponle ti ṣaájú sọ wí pé ìyàwó òun kò ní ẹ̀tọ́ láti kọ òun sílẹ̀ nítorí wí pé òun ń lù ú.

Ó ní wí pé kò ní ẹ̀tọ́ láti dágbé àti wí pé kò gbọdọ̀ fẹ́ ọkùnrin mìíràn yàtọ̀ sí òun, tó sì ti máa ń lọ sí ilé tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà láti lọ dúnkokò mọ́-ọn.

Àwọn ará àdúgbò gbogbo ìgbà tí wọ́n jọ wà pọ̀ ni Ponle máa ń lu Lateefat bi ìlù bàrà kódà ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń dé ilé ìwòsàn kó tó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀.

Oyeyemi ṣàlàyé wí pé ní ọjọ́bọ̀ tó kọjá ni Ponle lọ sí ilé Lateefat lati dúnkokò mọ wí pé òun máa sún ní ààyè ṣùgbọ́n tí Lateefat tètè fẹsẹ̀ fẹ.

“Ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ló tún padà lọ sí ilé Lateefat nígbà tí ìyẹn ń kírun lọ́wọ́, ó da epo bẹntiróòlù sí i lára tó sì dáná si mọ́ inú ilé.”

“Àmọ́ Lateefat sáré tètè so Ponle láṣọ mú kó tó jáde tí àwọn méjéèjì sì jóná papọ̀ kí àwọn ará àdúgbò tó díde sí wọn.”

“Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ní àwọn ará àdúgbò gbé àwọn méjéèjì lọ sí ilé ìwòsàn níbi tí wọ́n ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé Lateefat ti dágbére fáyé.”

Oyeyemi ní lẹ́yìn ìgbà náà ni wọ́n fa Ponle lé ọlọ́pàá lọ́wọ́.

Ó ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú ni Ponle náà jẹ́ Ọlọ́run nípè.

Bákan náà ló ní ìnà náà jó ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Lateefat lẹ́sẹ̀ tí òun náà sì ti wà ní ilé ìwòsàn.