‘Ọkọ̀ mi máà ń tẹ̀lé mi lọ rehearsal Onílù ká tó gbéyàwó àmọ́ bí mo ṣe kó wọlé tán báyìí, ó di nǹkan míì…’

Oluwakemi Famugbode amọ ti inagijẹ rẹ lori itage n jẹ Irawo kẹnu bọ ọrọ ilẹ kun lori nnkan ti obinrin to ba pe ara rẹ ni onilu tabi onijo n ri paapaa eyi to ba wa nile ọkọ ninu wọn.

Irawo ni nnkan ti oju oun ri fẹẹ mu ẹmi oun lọ nidi iṣẹ Onilu, DJ, ati Onimọran nipa iṣẹ ti orin n ṣe lara (Music Therapist).

“Ile ẹkọ girama ni mo ti bẹrẹ ilu lilu lẹyin ti mama mi ti kọ bi wọn ṣe n lu gangan lati kekere. Awọn to ju mi lọ ni ile ẹkọ n lu, wọn o lu u daadaa ni mo wa lọ gba a lọwọ wọn”.

Irawo Onilu

“Mo pada roo pe bi mo ba fẹ da yatọ, afi ki n pada sidi ilu gangan”.

Irawo ni inu oun ko dun si iṣẹ imọ iṣiro ti oun kọkọ n kọ ni Fasiti afi igba ti oun pada si ibi imọ Tiata.

Mo pada kọ ọkọ mi silẹ tori bo ṣe n ti mi mọle ki n ma baa lu ilu

Irawo Onilu

Irawo ni nnkan ti oju obinrin n ri nidi iṣẹ yii kii ṣe kekere paapaa ẹni to ba fẹ ọkọ to ba n jowu tabi ti ko nifẹ rẹ pẹlu iṣẹ to n ṣe.

“Haa, wahala ni o, ẹni ti mo fẹ, mo ro pe o n ti mi lẹyin ni tori o maa n tẹle mi lọ fun “rehearsal ki n to di iyawo ile rẹ, aṣe irọ ni o n pa.”

Irawo ni bi oun ṣe de ile tan bayii ni ọkọ oun yiwọ to ni rara, oun o gbọdọ lọ fun yala rehearsal ni tabi ode ere gan ti wọn ti pe e fun ti wọn yoo si sanwo iṣẹ fun un.

“Gbogbo awọn to n ba mi ṣiṣẹ lo ni wọn n fẹ mi, o bẹrẹ si ni ti mi mọle. Bi mo ṣe bẹrẹ si ni kuna lati le lọ fun ode ilu lilu niyẹn ti olgbaninimọran mi yoo maa bẹ wọ.”.

Igba to ya ni ara ni oun sọ pe o to gẹ bi ọkọ oun ko ba ti le gba oun tọwọ tẹsẹ pẹlu iṣẹ ti oun n ṣe torinaa o gba awọn obinrin nimọran

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí