Ojú wa rí, a ṣe IVF, oyún ìbeji bàjẹ́ kí á tó di ọlọ́mọ láyé – Adesua àti Banky W

Desua Etomi ati Banky W

Oríṣun àwòrán, Instagram/adesuaetomi

Gbajugbaja oṣere, Adesua Etomi ati ọkọ rẹ to jẹ olorin, Banky jẹri ni ṣọọṣi pe oju awọn ri ki awọn to di ọlọmọ laye.

Wọn ni awọn ṣe eto ati bimọ ti wọn n pe ni IVF, koda wọn ni Adesua loyun ibeji ṣugbọn oyun naa bajẹ mọ ọn lara.

Adesua ṣalaye pe oun loyun ibeji lẹyin tawọn ṣe IVF tan, awọn ọmọ naa si n dagba, koda wọn maa n ru ninu oun.

Ṣugbọn ”lọjọ kan ti a lọ fun ayẹwo nile iwosan ni dokita sọ fun mi pe awọn ọmọ naa ko mi mọ ninu mi.

Dokita sọ fun wa pe a gbọdọ ko oyun to ti bajẹ ọhun kuro ninu mi lai fi akoko ṣofo.

Emi ati Banky pinnu lati gbadura pe ki awọn mọ le maa mi pada ṣugbọn ọwọ ti bọ si ori,” Adesua lo sọ bẹẹ.

Banky W ni asiko naa lagbara pupọ foun ati iyawo ouj nitori ibanujẹ nla ni iṣẹlẹ naa jẹ fawọn mejeeji.

”Mo ranti pe mo mu Adesua lọ si oke lẹyin ti wọn ko inu rẹ tan, mo di i lọwọ mu lori aga nibi ti awa mejeeji ti sunkun.

Igbiyanju IVF nigba keji ko tiẹ ṣiṣẹ rara, awọn dokita ni ile ọmọ Adesua ko wa bo ṣe yẹ ko wa ati pe atọ Banky W naa ko ṣe daadaa mọ,” Banky W ṣalaye.

Lẹyin naa lawọn mejeeji pinnu lati maa lo oogun kankan mọ, ti wọn si fi igbagbọ sinu Eledua lori ati bimọ laye.

Adesua ranti pe wẹrẹ ni Ọlọrun ṣe e fawọn lọdun 2020 nigba ti awọn ko tiẹ ro rara.

Oba oke pada fi ọmọkunrin lanti lanti jinki idile naa eyi ti wọn pe orukọ rẹ ni Zaiah.

Adesua ni awọn pinnu lati sọ iriri awọn nitori ọpọ obinrin lo n la iru nkan bayii kọja ti wọn ko si le sọrọ sita.