Ọjọ́ méje ti pẹ́ jù láti wá ojútùú sí ìnira tí owó Náírà ń kóbá ará ìlú – Afenifere sí Buhari

Àwòrán Buhari àti Afenifere

Oríṣun àwòrán, Collage

Ẹgbẹ́ Afenifere ilẹ̀ Yorùbá ti sọ fún Ààrẹ Muhammadu Buhari pé ọjọ́ méje tó bèèrè fún láti wá ojútùú sí làásìgbò tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú lórí ọ̀rọ̀ owó Náírà tuntun ti pọ̀jù.

Afenifere nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ wọn, Jare Ajayi fi léde lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kejì ọdún 2023 ní ọjọ́ méje tí ààrẹ Buhari ń bèèrè fùn ṣàfihàn rẹ̀ pé ààrẹ kò tara sí wàhálà tí àwọn ènìyàn ń kojú láti rí owó ná.

Ajayi ní ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló ní owó nínú akoto àsùnwọ̀n báǹkì wọn àmọ́ tí wọn kò rí owó náà gbà èyí tó ń kó ọ̀pọ̀ ìnira bá wọn.

Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló ti nù, tí okoòwò mìíràn ti dojúdé nítorí àìrí owó ná, fún ìdí èyí, ọjọ́ méje tí ààrẹ Buhari dá tún mọ̀ sí pé kí wọ́n máa jẹ̀yà lọ fún ọjọ́ méje si.

Ajayi ṣèrántí pé ní ọjọ́ Ẹtì ni ààrẹ Muhammadu Buhari lẹ́yìn ìpàdé tó ṣe pẹ̀lú àwọn gómìnà lábẹ́ ẹgbẹ́ All Progressives Congress, APC ní kí ọjọ́ mẹ́wàá tí CBN fi kún gbèdéke ọjọ́ tí owó àtijọ́ yóò kásẹ̀ nílẹ̀ ni àwọn yóò wá ojútùú sí ìṣòro tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú.

Àwọn gómìnà ọ̀hún ló lọ bá ààrẹ láti ṣe àgbéyẹ̀wò gbèdéke tí wọ́n fún àwọn ènìyàn ìnira tí àwọn ń kojú náà ń pa iṣẹ́ rere tí ààrẹ ti se rẹ́ kúrò lọ́kàn àwọn ènìyàn.

Agbẹnusọ Afenifere ọhun fi kun pé kò jọ́ wí pé ààrẹ ní ohun pàtó kan tó fẹ́ ṣe lásìkò tó fi ọ̀rọ̀ náà léde nítorí kò jọ wí pé àyípadà kan gbòógì kan tó ti wáyé láti ìgbà náà.

Ó tẹ̀síwájú pé Afenifere wòye láti dá sí ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ nítorí ewu ńlá tá àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú nítorí ọ̀wọ́ngógó epo bẹntiróòlù àti owó Náírà.

Ó fi kun pé ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ báyìí ń fẹ́ àmójútó ní kíákíá nítorí àti dín ìdààmú àwọn ọmọ Nàìjíríà kù.

Ó ní ó ṣeni láàánú pé àwón ènìyàn ti pàdánù ẹ̀mí wọn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí níbi àwọn ìwọ́de tó wáyé ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo àti àwọn ìpínlẹ̀ kan ní orílẹ̀ èdè yìí.

Ajayi ní ọ̀pọ̀ àwọn tó lọ sí ilé ìfowópamọ́ láti lọ gba owó wọn ni wọ́n ń rí ìjákulẹ̀ nítorí báǹkì kọ̀ ;áti fún wọn ní iye owó tí wọ́n fẹ́ gbà dípò bẹ́ẹ̀ owó kékeré ni wọ́n ń fún wọn.

Bákan náà ló ní tó bá jẹ́ wí pé owó Náírà ti ń so èso rere èyí gómìnà ilé ìfowópamọ́ àgbà, Godwin Emefiele ní ó so, kò yẹ kí làálàá tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú pọ̀ tó bá yìí.

Ajayi tún ké sí àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́ àti àwọn mìíràn tí kò jẹ́ kí owó náà tàn kalẹ̀ láti jáwọ́ nínú ìwà bẹ́ẹ̀.

Ó ní ìwà bí àwọn ilé ìfowópamọ́ ṣe kò owó pamọ́ dípò kí wọ́n ko sínú maṣíìnì ATM wọn èyí fídíò rẹ̀ ti gba ìgboro kan kù díẹ̀ káàtó.

Ó parí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti rọ ààrẹ Buhari láti pàṣẹ fún CBN láti kó owó náà jáde lọ́pọ̀ yanturu kí ayé le di gbẹdẹmukẹ fún mùtúmùwà.