Ọ̀gá àgbà Iléeṣẹ́ ológun tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ àwọn èèyàn Tudun Biriin

Aworan ọga ileeṣẹ ologun

Oríṣun àwòrán, Nigeria Army

Oga agba ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria, Ọgagun Taoreed Lagbaja ti tọrọ aforijin lọwọ awọn eeyan agbegbe Tudun Biri nipinlẹ Kaduna fun isẹlẹ ibu gbamu to gba ẹmi ọpọlọpọ eeyan ti awọn mi si tun farapa yanayana.

Ninu atẹjade kan ti Ileeṣẹ ologun fi sori opo ayelujara wọn, Ọga ologun sabẹwo si agbegbe naa lati ba awọn ara agbegbe naa kẹdun lori isẹlẹ naa.

Ọgagun Lagbaja ni isẹlẹ naa waye lasiko ti ileeṣẹ ologun n se ọfintoto agbegbe ti wọn kẹfin awọn janduku, ti wọn si ṣeesi ju ado oloro si aarin awọn eeyan to n se ajọdun Maolud Nabiyy, ti wọn ro pe wọn jẹ janduku,

O fidi rẹ mulẹ pe iwadii ti bẹrẹ lati sawari ohun to sokunfa asise naa ati o ṣe koko lati se iwadi naa lati gbegi dena irufẹ isẹlẹ naa lọjọ iwaju.

Ọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lo ti fẹhonu wọn ran sita lori isẹlẹ ibu gbamu naa, ti Aarẹ Bola Tinubu si ti paṣẹ pe ki iwadi bẹrẹ ni kiakia.

Ajọ to n risi isẹlẹ pajawiri lorilẹede Naijiria, NEMA ni o ti to eeyan marundinlaadọruun to ti padanu ẹmi wọn lẹyin ibu gbamu naa, ti eeyan ọgọta si wa ni ile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju sugbọn awọn ajọ to n ja fẹtọ ọmọniyan gbagbọ iye eeyan to ku ju bẹ iyẹn lọ.

Èèyàn 85 ló pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìbú gbàmù Kaduna

Aworan Ileeṣẹ ologun

Oríṣun àwòrán, AFP

Ajọ to n risi isẹlẹ pajawiri nipinlẹ Kaduna ni o to eeyan marundinlaadọrun to padanu ẹmi wọn nibi isẹlẹ ibu gbamu ado oloro to waye nipinlẹ naa.

Ajọ naa ni eto isinku ti waye fun awọn eeyan naa ni agbegbe ilu Tudun Biriin nijọba ibilẹ Igabi nipinlẹ Kaduna, ti iwadii si ti bẹrẹ.

Saaju ni Ileeṣẹ ologun ofurufu Naijiria pariwo sita pe awọn ko mọ ohunkohun nipa bu gbamu naa.

Lanaa, Ọjọ Aje, ọjọ kẹrin oṣu kejila ọdun 2023, Ile igimọ aṣofin ile Naijiria palasẹ pe ki iwadii bẹrẹ lẹyin ti Ileeṣẹ ologun kede pe awọn ni wọn ju ado oloro naa si laarin awọn olujọsin nibi ayẹyẹ Maolud Nabiyy.

Aarẹ Tinubu ba awọn mọlẹbi kẹdun

Aarẹ Bola Tinubu ti ba awọn mọlẹbi awọn to padanu ẹmi nibiisẹlẹ ibu gbamu ado oloro to waye ni agbegbe Tudun Biriin nijọba ibilẹ Igabi nipinlẹ Kaduna.

Aare sapejuwe isẹlẹ naa gẹgẹ bi ohun to ba ni lọkan jẹ pupọ, to si tun gba oni je.

Aarẹ ninu atẹjade ti Oludamọran rẹ, Ajuri Ngelale buwọlu fun akọroyin ni oun ti paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ ni onikiakia, to rọ awọn araalu lati se suuru nitori awọn yoo ri pe otitọ farahan.

Bakan naa ni Aarẹ ni oun ti pasẹ ki itọju bẹrẹ fun awọn eeyan to farapa. To si tun gba ladura pe ki Ọlọrun forijin awọn to ti jade laye.