Ó ṣojú mi nígbà tí wọn dáná sun ọba, bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé rèé – Ẹlẹ́rìí

Ayinde Odetola

Oríṣun àwòrán, Ayinde Odetola

O ṣoju mi koro kan ti ṣalaye fun BBC bi awọn afurasi janduku kan ṣe ṣeku pa Ayinde Odetola, Oba ilu Agodo ni ijọba ibilẹ Ewekoro ni Ogun.

Arakunrin naa sọ pe oun, oriade naa ati awọn eeyan mii n ṣiṣẹ lori ilẹ ẹgbọn ọba lọwọ ni lasiko tawọn janduku naa ṣe ikọlu si wọn.

”A n ro oko lori ilẹ ẹgbọn Kabiyesi ti awọn kan pa laipẹ yi ni .Baa ṣe n ṣiṣẹ lọ, ọkan lara awọn janduku yi paṣẹ kawọn iyoku doju ija kọ wa”

“Bi mo ṣe n ba Kabiyesi sọrọ, awọn janduku naa kan fọ pako mọ mi ni. Wọn fi pako yii lu mi titi ti mo fi farapa.

Bi awọn eeyan ṣe n rin yika Kabiyesi lati daabo bo wọn, ọkan ninu awọn janduku yii ba da bẹntiroo si wọn lori .”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O tẹ siwaju pe ”Kabiyesi ja witiwiti lọ si idi ọkọ wọn nitori oju ti n ta wọn. Inu ọkọ yii ni wọn fọ pako mọ wọn lori ti wọn si daku sibẹ”

Arakunrin yii sọ pe lẹyin ti wọn lu Kabiyesi laludaku, wọn kọju si oun naa, ti wọn si n lu oun lalu sare.

“Wọn le mi wọ igbo ti mo si gba ibẹ jade si Oke Iganmu nibi tawọn ọlọpaa wa. Nigba ti mo de ibẹ, mo sọ fawọn ọlọpaa pe ki wọn jọwọ tẹle mi pada lati lọ doola Kabiyesi ṣugbọn awọn ọlọpaa lawọn ko ni le tẹle mi”

O ṣoju mi koro naa sọ pe oun ko si nibẹ nigba ti wọn dana sun ọkọ Kabiyesi

Ki lawọn ọlọpaa sọ nipa iṣẹlẹ yii?

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi sọ pe awọn gba ipe nipa iṣẹlẹ yii tawọn si tara lọ sibẹ.

O sọ fun BBC pe iwadii ti n tsiwaju ati pe Kọmisana ọlọpaa naa yọju sibi iṣẹlẹ naa.

Oyeyemi fi kun pe awọn ko tii mu eeyan kankan amọ awọn ti n ri awọn ẹri kan ati pe awọn ti n tọ pinpin awọn afurasi to mọ nipa iṣẹlẹ yi.

”A ti n ri awọn ẹri kọọkan to n tọ wa sọna taa si ti n tọ ipasẹ awọn to mọ nipa iṣẹlẹ yi.O dawa loju pe a o ri wọn mu”

Akọsilẹ awọn iṣẹlẹ ikọlu sawọn oriade ni Naijiria

Ni meni meji, iṣẹlẹ ikọlu sawọn oriade taa ri akọsilẹ wọn ni wọn yi.

Ọba David Oyewumi, to jẹ Obadu ti Ilemeso-Ekiti, ni awọn ajijigbe ji gbe ninu aafin rẹ to wa ni ijọba ibilẹ Oye, nipinle Ekiti.

Oṣojumikoro kan sọ pe awọn ajinigbe naa lu ori ade ọhun atawọn ẹbi rẹ ninu aafin, ki wọn to gbe salọ.

Lọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kẹrin dun 2021 ni wọn ji gbe.

Nigba to n fi idi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, Alaga igbimọ lọbalọba nipinlẹ Ekiti, Ọba Adebanji Ajibade Alabi, tii ṣe Alawe ti ilu Ilawe-Ekiti ni iṣẹlẹ naa jẹ eyii to buru jai o si ba awọn lọkan jẹ gidi.

O ni “awa gẹgẹ bii ọba, ati gbe igbesẹ lori iṣẹlẹ naa, nitori ni kete ti a gbọ ni mo ke si ileeṣẹ ọlọpaa, awọn fijilante atawọn ikọ Amọtẹkun lati wọ inu igbo ti wọn gbe ọba naa lọ, lati wa a ri.”

Kabiyesi pada gba itusilẹ loṣu Kẹrin yi kanna ṣugbọn Kabiyesi pẹ ni ile iwosan nibi ti wọn ti gba itọju

Amin iyasọtọ kan

Losu Kọkanla ọdun to kọja, awọn agbebọn kan ji Oba ilu Ogwaniocha nijọba ibilẹ Ogbaru gbe ni Anambra.

Awọn agbebọn yi to ṣe ikọlu si aafin Oba s ina sibẹ lasiko ikọlu yi..

Amọ ikọ kogberegbe awọn ọmọ ogun oju omi Naijiria to wa ni Onitsha wọ igbo Ochan lọ ti wọn si mu lara awọn afurasi yi.

Ọwọ wọn tẹ awọn afurasi meji-Victor Ibenegbu ati Egbuna Anyakoha-ti wọn si jẹwọ ipa ti wọn ko ninu ikọlu yi.

Alayee ti wọn ṣe nipa iṣẹlẹ naa lọ bayi pe ”A ji ọba yi gbe nitori ko jẹ ki a ni ipin ninu owo epo rọbi ti o n bọ si ọwọ ilu wa”

Amin iyasọtọ kan

Ninu iṣẹlẹ miran, awọn ikọ ọlọpaa ni ipinlẹ Imo ribi dina ikọlu kan to waye laafin alaga igbimọ lọbalọba Eze Emmanuel Okeke ni Ezioha Amaifeke, ijọba ibilẹ Orlu.

Ọjọ Kẹrin oṣu Kini ọdun yi ni iṣẹlẹ yi waye.

Alukoro ọlọpaa Imo, Micheal Abattam sọ ninu atjade pe ibọn jagamu lawọn afurasi yi fi ṣe ikọlu si aafin.

O sọ pe ”Awọn agbebọn yi ti wọn p gaan ko orisirisi ibọn lati wa fi ṣe ikọlu si aafin ṣugbọn a bori wọn pẹlu nkan ija tiwa”

O fi kun pe ”A ribi pa awọn kan ninu wọn tawọn mii si gbe ọgbẹ ọta ibọn sa wọ igbo lọ”