NÍ YÀJÓYÀJÓ NLC wọ́gilé ìwọ́de tó yẹ kó wáyé nítorí “Subsidy” owó epo bẹntiró

Ẹgbẹ awọn darandaran, Miyetti Allah, MACBAN, ti kede atilẹyin rẹ fun
asiwaju ẹgbẹ́ oselu All Progressives Congress, APC, Bola Tinubu, lori erongba rẹ
lati dije fun ipo aarẹ lọdun 2023.

Nibi ipade ẹgbẹ́ naa ti wọn ṣe nilu Abuja lọjọ Aiku ni ẹgbẹ Miyetti Alaah ti fi ẹnu ọrọ jona bẹẹ.

Oludari ipade naa, Ya’u Haruna salaye pe ilanilọyẹ ti n lọ fun awọn eniyan ẹ̀yà
Fulani lori eto idibo ọdun 2023, eto aabo ati bi wọn o ṣe ma a gbe ni alaafia pẹlu
awọn aladugbo wọn.

O ni awọn ti n sakiyesi àwọn to fẹ dupo aarẹ pẹlu Tinubu.

“Tinubu lo n leke, nitori oun lo dasi wahala to de ba wa nipinlẹ
Benue, lasiko to fi jẹ gomina ipinlẹ Eko.

” O gbera lati ipinlẹ Eko wa si Benue, o pé gbogbo awa ti ọrọ kan si
ipade ijiroro, o si ba wa laja.

“Igbagbọ wa ni pe ẹni to le ṣe iru nkan bẹẹ yoo ṣe ju bẹẹ lọ to ba de
ipo isakoso.

Olori Fulani naa sọ pe o jẹ ibanujẹ pe oju ọ̀daràn ni wọn fi n wo ẹ̀yà naa
ni Naijiria bayii, bo tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ wọn kii ṣe ọ̀daràn.

Copyright: Bola Tinubu and Miyetti Allah