NÍ YÀJÓYÀJÓ Ẹ̀fọn Japan já bàálù Germany lúlẹ̀ ní Qatar 2022

Copyright: FIFA

Ajọ ere bọọlu lagbaye, FIFA ti sọ pe nnkan
bii miliọnu mẹta tikẹti iworan bọọlu fun ife ẹyẹ agbaye lawọn ti ta fun awon eeyan kaakiri.

Agbẹnusọ kan fun ajo so fun ileeṣẹ
akoroyinjọ AFP pe titi di ọjọ Aiku tikẹẹti iworan ti iye rẹ je milionu mẹta o
din marun, (2.95 million) ajo naa ri ta.

Ọjọ Aiku ni idije ife ẹyẹ agbaye bẹrẹ
lorilẹede Qatar eti to ti mu ki ariwo ife ẹyẹ naa tun pọ sii lori ayelujara bi
o tilẹ je pe oniruuru iroyin odi nipa fifi aye gba Qatar lati gbalejo idije naa
lo jade.

Ifesewonse mẹrinlegota ni yoo waye laarin
ọjọ mokandinlogbon ti yoo waye nibẹ.

Nṣe lawọn eeyan n to kaakiri awọn ibudo ti
ajọ FIFA ti ya sọtọ fun tita ati rira awọn tikẹti iworan bọọlu naa ni ilu Doha.

Nibayii iye tikẹti iworan ti wọn ta ni
Qatar ti gbẹnisoke ju ti Russia lọdun 2018 lọ bayii. Irinwo o le miliọnu meji
ni tikẹti iworan lodun 2018.

Agbẹnusọ fun FIFA naa sọ pe, Qatar, Saudi
Arabia, Amẹrika, Mexico, ilẹ Gẹẹsi, United Arab Emirate, Argentina, France, ati
Brazil lawọn eeyan ti ra tikẹti iworan yii julo.

Aarẹ ajọ FIFA, Giovanni Infatino ṣalaye
nibi apero kan pe iye owo ti won n reti lati pa wọle lọdun mẹrin -merin yoo wọ
biliọnu meje abọ dola lọdun yii.

Eyi yoo fi biliọnu kan pọ ju iye ti wọn
f’ọkan sí lọdun mẹrin sẹyin.

Infatuno sọ pe, iye to wole naa jọ oun loju
pẹlu gbogbo ipenija ajakalẹ arun COVID19 at’awọn wahala kaakiri agbaye.

O ṣeeṣe ki wọn tun Infatino yan gẹgẹ bi
aarẹ ajọ FIFA loṣu kẹta odun to n bọ.

O ni awọn ofin tuntun to de awonmanija egbe
yoo jade lọdun to n bo.

Infatino tun sọ pe oun fẹ tubọ fẹ ki
Ifesewonse laarin orilẹede lati ẹkun ọtọọtọ ati fifẹ idije ife ẹyẹ agbaye loju
sii.