NÍ YÀJÓYÀJÓ Àrùn Corona padà bú jáde ní China, èèyàn 31,527 lùgbàdì rẹ̀ lọ́jọ́ kan ṣoṣo

Copyright: OTHERS

Gbogbo ilu lo pa lọlọ lati owurọ kutu oni ti iroyin iku
Ifeanyiọmọ ọdun mẹta gbajugbaja olorin,
David Adeleke ti ọpọ mọ si Davido ati Chioma gba ori ayelujara.

Lati oru ni awọn eeyan ti n figbe ta lori ayelujara pe ọkan
awọn ko balẹ lori iroyin bi yoo ye tabi ko ni ye ti wọn si n gbohun adura soke.

Amọ kete ti aridaju iroyin iku rẹ jade ni owurọ
ni ọpọ eniyan ti n ba idile naa kẹdun.

PDP
Oṣun dawọ eto ọsẹ yii duro

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ni ipinlẹ Oṣun ti fi atẹjade
sita pe gbogbo eto ti awọn la kalẹ fun ọsẹ yii ko ni waye mọ.

Niu atẹjade naa ti Ọmọwe Adekunle Akindele to jẹ alaga igbimọ
amuṣẹya fọwọ si, ẹgbẹ naa ni latari ajalu to de ba eekan inu idile Adeleke,
David Adeleke ni awọn fi so gbogbo eto rọ nipinlẹ naa ti wọn si pa a laṣẹ fun
gbogbo igun ẹgbẹ naa ati igbimọ rẹ kaakiri ipinlẹ Oṣun latima ṣe eto kankan lati lee ba ẹbi naa kẹdun.

“A daro ipapoda ọmọ wa, Ifeanyi to ba wa lọkan jẹ gidi gan.
A gbadura fun ẹmi rẹ. Ọjọ buruku ni eyi ṣugbọn a duro ṣinṣin ninu igbagbọ wa
ninu Ọlọrun gbogbo aye.

Ọkàn wá wà pẹ̀lú Davido aṣojú ọ̀dọ́ wa àti ẹbí rẹ̀
lórí ikú ọmọ wọn. A bá ẹni tó dúro fún wa bíi bàbá, Ọmọwe Deji Adeleke ati
gbogbo ẹbi Adeleke lapapọ. A gbaduro pe Ọlọrun yoo fun ẹbi naa ni okun lati
bori adanu nla yii.”

Bola
Ahmed Tinubu

Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives
Congress, Bola Ahmed Tinubu sọrọ ibanikẹdun to si fi adura ranṣẹ si Davido ati ẹbi
rẹ.

“Emi ati Oluremi fi ibanikẹdun wa tọkan tọkan ranṣẹ si
David, Chioma ati gbogbo idile Adeleke lori pipadanu ọmọ wọn Ifeanyi.

Ọkan wa ati adura wa wa plu ẹbi naa. Ọlọrun yoo fun wọn ni
oku lati bori iṣẹlẹ aburu yii.”

Bi Bola Tinubu ṣe fi eyi sita loju opo Twitter rẹ
naa ni awọn ọmọ Naijiria ti fesi sii pẹlu imoore ati oniruuru ero tiwọn.

View more on twitter

Peter Obi

Oludije sipo aarẹ lẹgbẹ Oṣelu Labour Party, Peter Obi ni oun
ko tilẹ le woye iru nkan ti ẹbi Adeleke n la kọja bayii, o fi ibanikẹdun ranṣẹ
o si tun gbadura fun wọn.

“Mo fi ibanikẹdun mi ranṣẹ si Davido ati Chioma lori iku ọmọ
wọn Ifeanyi. Mi o le ro iru ohun ti wọn n la kọja bayii. Ki Ọlọrun fun wọn ni
iwosan, okun ki o si tu wọn ninu ni asiko adanwo yii. Ọkan mi ati adura mi wa pẹlu
ẹbi naa – PO”.

Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo fesi si atẹjade yii lori
ayelujara.

View more on twitter

Atiku
Abubakar

Bakan naa ni oludije sipo aarẹ aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples
Democratic Party, Atiku Abubakar naa fi ọrọ ibanikẹdun rẹ ranṣẹ si Davido ati ẹbi
rẹ to si ni “Ọkan mi ati adura mi lọ sọdọ David ati Chioma ati gbogbo ẹbi
Adeleke lasiko yii. Mo gbadura ki Ọlọrun fun wọn ni okun ko si ti wọn ninu – AA.

Bẹẹ naa ni ọpọlọpọ ọmọ Naijiria fesi si atẹjade
yii lori ayelujara.

View more on twitter

Copyright: OTHERS

Bakan naa ni ọkan lara awọn gbajugbaja olorin, Waje fi sita
latari gbogbo oniruuru ọrọ alufansa to n ti ẹnu awọn mii jade lori iṣẹlẹ aburu
naa pe:

“Ṣe ẹ kan le gbadura fun idile David ati Chioma ki ẹ si jẹ
ki wọn mọ pe a wa nibi fun wọn. Gbogbo ohun ti wọn nilo lasiko yii niyẹn. Ifẹ
ati atilẹyin. Ẹ jẹ eeyan didara si ọmọlakeji.”

Ni owurọ yii ni ileeṣẹ ọlọpaa fi esi sita pe
lootọ ni ọmọ naa ti ku ti awọn si ti fi ofin gbe oṣiṣẹ mẹjọ ni ile Davido lati
fi ọrọ wa wọn lẹnu wo lori ohun to ṣokunfa iku naa ati bo ṣe ṣẹlẹ.

View more on twitter