NÍ YÀJÓYÀJÓ Akọrin ọmọ Nàíjíríà, Tems, gbàmì ẹ̀yẹ Grammy

Copyright: Others

Bi ọdun tuntun, oṣu
tuntun ṣe n bẹrẹ bayii ni awọn eniyan ti n ni ọpọlọpọ ẹrongba ati awọn ohun ti
wọn ni lọkan lati ṣe.

Amọ lati mu awọn
erongba yii wa si imuṣẹ, o di dandan lati fi owo pamọ.

Nitori naa, ti o
ba n gbero ọna lati fi owo pamọ ki o le da nkan rere ṣe ni ọdun 2023, wa si
ihinyii lati wo awọn igbeṣẹ to yẹ ki o gbe

Ninu ifọrọwerọ
yii ni onimọ nipa eto iṣuna,Abilekọ Uche
Iheanacho ti salaye ọna
ti awọn eniyan le gba lati fi owo pamọ

Ohun akọkọ ni ki
o jẹ olootọ si ara rẹ:

O dara lati sọ
otitọ fun ara ẹni lori ipo ti eto iṣuna rẹ wa. Iye owo wo ni yoo ṣeeṣe fun ọ
lati fipamọ ninu ọdun tuntun? Awọn wo ni oun toju to n gba owo lọ ni ọwọ rẹ? Ati
pe ki ni o le ṣe lati fi owo pamọ ju ti tẹlẹ lọ?

Ni nkan ti o fẹ
fi owo ṣe lọkan:

Gẹgẹ bi onimọ
nipa eto iṣuna ṣe ṣalaye, lati fi owo pamọ, o di dandan lati ni lọkan ohun ti o
fẹ fi owo ṣe.

Ẹni to ba ni ohun
to fẹ fi owo ṣe ni ọkan ni ko ni na owo ni inakuna.

Bakan naa ni
eniyan gbọdọ mọ ohun to fẹ ṣe, kii ṣe ki o maa ṣiṣẹ tisa, ko o si fẹ ra ọkọ
baalu, iyen to bara jọ rara.

Nitori naa ti
eniyan ba ti ni ẹrọngba nkan to fẹ fi owo naa ṣe ni ọkan, ko ni nira lati ṣe aṣeyọri.

O pọn dandan lati
ṣe akọsilẹ awọn ohun to n gba owo lọwọ rẹ:

Abilekọ Iheanacho
salaye pe o pọn dandan lati fi eto si bi owo ṣe n jade ni ọwọ eniyan.

O ni awọn nkan ti
eniyan n na owo le lori ni oṣooṣu gbọdọ wa ni akọsilẹ to fi mọ eleyii ti a fi n
ṣe ayẹyẹ.

Ẹlomiran le sọ wi
pe ida ogun owo to n wọle si ohun lọwọ ni ohun fẹ fi si ipamọ, ki ohun si fi
iyoku owo naa ṣe awọn ohun to fẹ ṣe.

Ma nawo kọja owo
oṣu rẹ:

Awọn eniyan ma n
pa ni owe pe ki eniyan ma ṣe ju ara rẹ lọ.

Fun apere, ma gbe
ni agbegbe ti o ko ni le san owo ile rẹ. Ti ile nla ba n wu ọ lati gbe, ohun ti
o le ṣe ni lati fi si ọkan rẹ pe waa gbe igbeṣẹ naa ni ọjọ iwaju.

Fi imọ kun imọ rẹ:

Awọn nkan miran
ti o le ṣe lati jẹ owo to n wọle fun o ni oṣu pọsi ni koo ṣe.

”O le ka iwe si,
ki o kẹkọ ti yoo mu ki o ni itẹsiwaju si ni ẹnu iṣẹ rẹ.”

”Bakan naa ti o ko
ba ni iṣẹ, wa iṣẹ ti awọn eniyan n wa lati ṣe ki o le rọrun fun o lati ri iṣẹ.”

Wo aṣeyọri rẹ:

Lati igba de igba
o dara lati wo bi o ṣe n ṣe si ni igbiyanju rẹ lati fi owo pamọ.

”O dara lati ṣe awọn
akiyesi wọn yii ki ẹni naa le ma boya ohun ṣe aṣeyọri abi o ni ifaṣẹyin.”

”Ti o ba wo igbeṣẹ
rẹ, ti o si ri pe o ko ṣe to bi o ti yẹ, ma ba ọkan jẹ, amọ tẹsiwaju lati ṣe
ohun to tọ.”

Arabinrin onimọ
nipa eto iṣuna naa fi da awọn eniyan loju pe, ti wọn ko ba wo ẹyin ninu gbogbo
igbeṣẹ wọ, wọn yoo ṣe asẹyọri bi o ti yẹ.