‘Nàiìjíríà ti pèsè ”Private jet” tí yóò gbé Igboho padà sílé láti Cotonou sílẹ̀ kí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀’

Awọn ọdọ gbe bana Sunday Igboho dani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajijagbara ati ajafẹtọ nilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ṣi wa ni atimọle amọ kii ṣe ahamọ ọlọpaa lo wa mọ.

Ile ẹjọ lo paṣẹ nibi igbẹjọ rẹ lọjọ Aje pe ki wọn mu Igboho kuro ni atimọle ọlọpaa.

Awọn ikọ agbẹjọro to n ṣoju Igboho ni Cotonou ṣalaye pe ijọba Naijiria ti n gbe baalu agberapa kan kalẹ lati gbe Igboho pada si Naijiria lati wa jẹjọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ṣugbọn ọrọ Igboho yatọ si ti olori ẹgbẹ IPOB, Nnamdi Kanu nitori ijọba orilẹede olominira Benin da si ọrọ tiẹ.

Adehun ti Naijiria atawọn orilẹede iwọ oorun Afirika bii Togo, Benin ati Ghana jọ ṣe lọdun 1984 ko sọ pe ki wọn jọwọ awọn eeyan ti wọn ba n wa lori ọrọ oṣelu.

Awọn agbẹjọro Igboho sọ pe adehun ati ofin yii daabo bo Igboho.

Wọn tun sọ pe ofin ajọ ilẹ Afirika, AU faye gba ki eeyan pe fun iyapa lati ara orilẹede kan.

Ati wi pe Naijiria ati Benin wa lara orilẹede mẹẹdogun ọmọ ẹgbẹ ajọ ECOWAS eyi ti alakalẹ oniruuru ofin n dari.

Gẹgẹ bi alakalẹ ofin ECOWAS lori fifi awọn awọn afurasi ọdaran ranṣẹ si orilẹede abinibi wọn, ijọba orilẹede wọn gbọdọ sọ ẹsun ti wọn fi ṣẹ si ofin ki wọn si beere pe ki wọn jọwọ ẹni bẹẹ.

Ile ẹjọ nikan lo le sọ bo ya orilẹede kan yoo jọwọ afurasi ọdaran fun orilẹede abinini wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ṣe orilẹede Naijiria ti sọ fun Benin lati fi Sunday Igboho ranṣẹ?

Awọn kan ti fẹsun kan ijọba Naijiria pe o n fẹ lo agbara rẹ lati jọ ki Benin da Igboho pada lai fi ọwọ ofin bọ ọrọ naa tabi gbe lọ si ile ẹjọ.

Gbajugbaja agbẹjọro, Femi Falana sọ fun BBC pe ile iṣẹ aṣoju ijọba Naijiria kọ lẹta ranṣẹ si ijọba Benin pe ki wọn jọwọ Igboho fawọn.

Ṣugbọn ijọba ko gbe igbesi yii ni ilana ofin, ijọba Naijiria beere lai fi ti ofin ṣe.

Kinni ibaṣepọ to wa laarin Naijiria ati orilẹede Benin?

Ibode da Naijiria ati orilẹede Benin pọ ki ijọba Naijiria to gbe ibode rẹ tipa lọdun 2019.

Naijiria fẹsun kan Benin nigba naa pe o n ṣe fayawọ oriṣiiriṣii nkan ti ko ba ofin mu wọ Naijiria.

Ọrọ ibode ti Naijiria tipa lo mu ki Aarẹ Benin, Patrice Talon ṣe abẹwo si Naijiria lori ọna ati ṣi ibode ọhun pada.

Maapu Naijiria ati Beni

Oríṣun àwòrán, Other

Ibode naa si wa ni titi pa titi di ibẹrẹ ọdun 2021 yii.

Agbẹjọro Falana gbagbọ pe Naijiria ni lati kọ ẹkọ lori igbẹjọ Igboho ni Benin lori ọwọ ti orilẹede naa fi mu ẹtọ ọmọniyan.

Falana ni iyawo Igboho ti wọn mu pẹlu gba ominira ni kiakia lẹyin ti ileẹjọ sọ pe ko ṣẹ si ofin.

Gbajugbaja agbẹjọro naa sọ pe eyi yatọ si ọrọ awọn eeyan mejila ti wọn ko nile Igboho eyi ti wọn tii ko lọ si ile ẹjọ di akoko yii lẹyin ọsẹ diẹ ti wọn ti mu wọn sẹyin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ