“Mùsùlùmí ni Tani Olorun tẹ́lẹ̀, ọdún kẹta sẹ́yìn ló di onísẹ̀ṣe, mo sì rí ọwọ́ Ọlọ́run láyé rẹ̀”

Nofisat ati azeez Adegbola

Nofisat Adegbola, tii se iya oniṣẹṣe kan, Abdulazeez Adegbola, tawọn eeyan mọ si Tani Olohun, to wọ wahala nitori awọn ọrọ ibanilorukọjẹ to n sọ lori ẹrọ ayelujara, ti salaye awọn ohun to la kọja nipa ohun to n sẹlẹ si ọmọ rẹ.

Lasiko to n ba iwe iroyin Punch sọrọ, Nofisat ni igba mẹta ọtọọtọ ni oun ṣe igbọnsẹ sara ni alẹ ọjọ ti oun gbọ pe awọn ọlọpaa mu ọmọ ohun.

O ni ero ọkan oun ni pe ṣe ni wọn ji Tani Olohun gbe.

Nigba ti iya naa n sọrọ ninu ile rẹ ni agbegbe Molete nilu Ibadan, nibi ti oun, iyawo Tani Olohun atawọn ọmọ rẹ meji n gbe, iya naa wi pe “Nigba ti ko pada wale lalẹ ọjọ ti a n wi yii, aimọye igba ni mo tọ, ti mo tun ṣe igbọnsẹ sara.

“Ọjọ keji ti wọn ti gbe e lọ ni mo to gbọ, ko si ẹni to mọ ohun to n ṣẹlẹ titi ọjọ keji ti wọn ti gbe e lọ ilu Ilorin.”

Nofisat Adegbola

Báwo ọ̀rọ̀ náà ṣe bẹ̀rẹ̀?

Abdulazeez Adegbola, ti awọn eeyan mọ si Tani Olohun, to jẹ gbajugbaja oniṣẹṣe lori ayelujara, ni awọn ọlọpaa mu nilu Ibadan, ti wọn si gbe lọ si ilu Ilorin labẹ idari kọmiṣọna fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara.

Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni Tani Olorun, ti wọn si fi ẹsun ibanilorukọjẹ ati sisọ ọrọ abuku si Emir ilu Ilorin, Alhaji Ibrahim Sulu-Gambari atawọn aafaa mii ni ipinlẹ naa, pẹlu awọn ẹsun miran.

Gbogbo awọn ẹsun yii, gẹgẹ bii Ademola Banks to jẹ agbẹjọro olujẹjọ naa ṣe wi, ni wọn lee gba oniduro fun nile-ẹjọ amọ inu galo ni Tani Olohun wa lati ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹjọ.

“Nọọsi fa omi si mi lara tori omi to pọ gbẹ lagọ ara mi, mo tọ, mo si tun yagbẹ sara”

Iyaafin Adegbola wi pe Tani Olohun dagbere fun oun ni nkan bii aago mẹfa ku iṣẹju mẹta nirọlẹ ọjọ isinmi naa pe, oun fẹ de Moboluwaji, ti oun si wi fun pe ko mase pẹ nita ati pe ko ra nkan bọ.

“Awọn ọmọ mi kii pẹ nita nitori wọn mọ pe maa ti ṣọọbu lẹyin irun alẹ, to si jẹ pe a gbọdọ dijọ kirun pọ ni ati pe wọn ti gbọdọ wa ninu ile ki n too ti ṣọọbu.

“Nigba ti mo reti titi ti ko de, mo rin de itosi Odo-oba lati wo o boya mo maa pade rẹ lọna amọ nko ri ẹni to jọ ọ.

“Ni gbogbo akoko yii, iporuuru ọkan ti de ba mi tori n ko mọ boya wọn ti jii gbe ni.

“Kia ni mo pada sile lati lọ ọ ji gbogbo ile pe nko ri Azeez (Tani Olohun) tori ko rin iru irin bẹẹ ri.

“Idaamu yii mu ki n maa ya igbẹ gbuuru lẹsẹkẹsẹ, ti mo si ṣe eyi sara lọpọ igba.

Koda, nọọsi fa omi si mi lara laarọ ọjọ keji nigba to wi pe mo ti padanu omi to pọ lagọ ara mi.”

“BBC Yoruba lo jẹ ka mọ pe awọn ọlọpaa lo mu Azeez to tun n jẹ Tani Olorun”

Iya a Tani Olohun ṣe alaye pe ninu iroyin ni awọn mọlẹbi ti gbọ pe ọlọpaa lo mu ọmọ oun.

O wi pe “aburo rẹ lo waa sọ fun mi pe oun kaa lori ikanni BBC Yoruba pe wọn mu Azeez n’Ibadan, wọn si ti gbee lọ Ilorin.

“O ni oun wa bun mi gbọ ni, ti oun yoo si gbera lẹsẹkẹsẹ lati maa lọ ilu Ilorin, amọ ko too de bẹ, wọn ti ran Azeez ni ẹwọn aadọta ọjọ.

“Lati igba yii ni ọmọ mi ti wa lẹwọn, to si ti n lo oṣu kẹta lọ.”

“Mo sunkun nigba ti mo lọ bẹ Azeez wo lọgba ẹwọn, o ti ru, apa ati ẹsẹ rẹ ti tiirin”

N ṣe ni iyaafin Adegbola bu sẹkun nigba to fẹ sọrọ nipa abẹwo rẹ si Tani Olohun lọgba ẹwọn.

O wi pe “n ṣe mo n sunkun nigba ti mo rii. Ko jọ ọmọ mi mọ. O ti ru gan. Apa ati ẹsẹ rẹ ti ri tiirin.

“Wọn ti lu u, ti wọn si fiya jẹ ẹ daaadaa.

Ẹsẹ ati ọrun ọwọ rẹ ti wu. Inu inira lo wa.

N ṣe ni mo ṣa n sunkun nitori ọmọ mi kọ ni mo n wo niwaju mi.”

“Mo lọ bẹ awọn Afaa ni Ilorin pe ki wọn wo ọla pe mo jẹ Musulumi mọ mi lara amọ wọn ko se bẹẹ”

Ni ọsẹ diẹ sẹyin ni BBC Yoruba ya aworan bi mama Nofisat Adegbola se n bẹ awọn aafaa Ilorin pe ki wọn dari jin ọmọ, eyi to gba ori ayelujara.

Adegbola ṣe alaye pe “funra mi ni mo gbe ara mi lọ ba awọn aafaa ni Ilorin lati lọ bẹ wọn pẹlu igbagbọ pe wọn yoo wo ijẹ Musulumi mi lati fori jin ọmọ mi.

“Erongba mi ni pe wọn yoo wo ọla mi mọ ọmọ mi lara amọ ko ri bẹẹ.

Lẹyin ni eyi ni awọn ẹgbẹ Musulumi kan tun gbe ẹjọ miran dide pe o dana sun alukurani.

“Awọn ẹgbẹ iṣẹṣe ti gbiyanju. Wọn sanwo fun agbẹjọro Olobi, wọn si n ṣeto bi ọmọ yoo ṣe maa jẹun lojoojumọ.

Iya naa to wi pe worobo ti ohun n ta ko to nkan, fikun pe, ọkọ oun ti ku lati bii ọdun mẹta sẹyin, to si jẹ pe oun nikan ni oun n tọ awọn ọmọ oun.

O wipe koda, n ṣe ni oun yawo lati wọ ọkọ lọ ọ bẹ awọn aafaa n’Ilorin, to si jẹ pe awọn oniṣẹṣe lo n ṣe gbogbo ohun to tọ lati mayedẹrun fun Tani Olohun lọgba ẹwọn ati lati ripe o gba ominira laipẹ ọjọ.

“Musulumi ni ọmọ mi, ko too di oniṣẹṣe”

Iyaafin Adegbola wi pe ni nkan bii ọdun mẹta sẹyin ni ọmọ ohun di oniṣẹṣe.

Iya naa wi pe “ni nkan bii ọdun mẹta sẹyin lo sọ fun mi pe ohun ti di oniṣẹṣe, to si dun mi gidi.

“Ọrọ naa fa ariyanjiyan to pọ laarin wa, amọ mo fi silẹ lẹyin ti mo bẹrẹ si nii ri ọwọ Ọlọrun laye rẹ.

“Gbogbo igba lo maa n wi pe Olodumare ni ki n ṣe eleyi, Olodumare ni ki n ‘se tọhun.

O fara jin fun mimọ Olorun ni ilana ẹsin rẹ tuntun yii, mo si ri ọwọ Olorun laye e rẹ.”

“Mi o gbadun, mo kan maa n sunkun lojoojumọ lati igba ti wọn ti wọn ti mu ọkọ mi – iyawo Tani Olohun

Ṣaaju itusilẹ Tani Olohun ni Rasheedat Adegbola, to jẹ iyawo rẹ ti wi pe nkan ko rọrun lati igba ti wọn ti mu ọkọ oun.

Rasheedat wi pe “mi o gbadun. Mo kan maa n sunkun lojoojumọ lati igba ti wọn ti wọn ti mu ọkọ mi ni.

“Ọkọ mi jẹ iru ọkọ ti obirin fi n tọrọ ọkọ. Ohun to jẹ ẹ logun ni lati mu inu mọlẹbi rẹ dun.

“Nọọsi ni mi. Igba ti mo wa nile-ẹkọ la pade ni nkan bii ọdun mẹfa sẹyin lọdọ ẹgbọn mi, a si ti bimọ meji fun ara wa.

“Musulumi ni ọkọ mi nigba ta a pade amọ ni nkan bii ọdun mẹta sẹyin lo di oniṣẹṣe.