“Mo padanu isẹ mi tori n ko gba abẹrẹ àjẹsára Covid-19”

Abẹrẹ Ajẹsara Covid-19

Ni orilẹede Naijiria, ọpọ eeyan ni ẹru n ba lati gba abẹrẹ ajẹsara to n gbogun ti aisan Coronavirus, ti awọn eeyan kan si n fi aake kọri pe awọn ko ni gba abẹrẹ naa.

Ijọba apapọ gan ti kede pe abẹrẹ ajẹsara yii ti di ọranyan fun awọn osisẹ ọba atawọn eeyan to fẹ wọnu awọn ileesẹ ijọba.

Gbogbo wọn si lo gbọdọ fi iwe ẹri han pe wọn ti gba abẹrẹ naa tabi se ayẹwo pe awọn ko ni arun Covid-19, ki wọn to le wọnu ọọfisi ijọba.

Ọpọ ariwisi ati ifẹhonu han lori ayelujara si lo tẹle ikede naa, tawọn araalu si ni igbesẹ naa tako ẹtọ ọmọniyan lati se ohun to ba fẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Obinrin kan padanu isẹ rẹ tori ko gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19:

Amọ bi o tilẹ jẹ pe awọn eeyan mu iwa yii jẹ ni Naijiria, ti ko si si nnkan kan to ti ẹyin rẹ yọ, amọ obinrin kan ree nilẹ Amẹrika, ti ọrọ naa yiwọ fun.

Danielle Thornton ati ọkọ rẹ ni wọn pinnu pe awọn ko ni gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 naa, ti wọn si fi ọwọ lẹran maa woye ohun ti yoo tẹyin igbesẹ naa yọ.

Koda, o han gbangba si wọn pe o seese ki awọn padanu isẹ oojọ awọn, ti awọn ko ba gba abẹrẹ naa.

Gẹgẹ bi Danielle ti wi, oun ati ọkọ oun jiroro pupọ lori igbesẹ gbigba abẹrẹ ajẹsara naa, ti awọn si fi ẹnu ko pe ominira awọn se iyebiye ju owo osu lọ.

Obinrin yii si lo jẹ ọkan lara ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan ni Amẹrika to fara mọ pe ki awọn sọ isẹ nu ju ki awọn gba abẹrẹ Covid-19 lọ.

Iru awọn eeyan ti ko gba abẹrẹ yii si ni wọn kere niye bii ida mẹẹdọgbọn ninu ọgọrun eeyan to wa ni orilẹede Amẹrika.

The Banki Citigroup ti Danielle ti n sisẹ, ida kan osisẹ wọn lo kọ lati gba abẹrẹ naa, ti awọn yoku si ti gba a eyi ti wọn ni yoo dena ewu pupọ.

Ni osu January yii, ile ẹjọ to ga julọ nilẹ Amẹrika wọgile ofin kan ti aarẹ Joe Biden gbe wa siwaju rẹ.

Biden ni oun n fẹ ki o kere tan, ọgọrun eeyan nibi isẹ kan, ti gba abẹrẹ ajẹsara naa, tabi maa lo ibomu loore koore tabi maa se idanwo ayẹwo Covid-19 lọsọọsẹ pẹlu owo apo wọn.

Ki lo de ti awọn eeyan kan ko se fẹ gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19?

Gẹgẹ bi Danielle ti wi, oun kii se oloselu, bẹẹ ni oun ko tako igbesẹ gbigba abẹrẹ ajẹsara naa nitori oun ti gba tẹlẹ nigba ti abẹrẹ naa sẹsẹ de.

Amọ o ni oun ni ẹtọ lati yan oun ti oun n fẹ, ti igbesẹ oun lati padanu isẹ oun yoo si nipa nla lori mọlẹbi oun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ