
Oríṣun àwòrán, OSARIEME EWEKA
Orogbo, ti awọn kan n pe ni Garnicia Kola, jẹ ohun ọgbin kan to maa n hu ni iwọ-oorun Afrika, ti wọn si maa n lo irugbin rẹ fun agbo lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin.
Orogbo ni ọpọlọpọ anfaani fun ilera. Ninu akọsilẹ yii, a o wo irugbin pataki yii ati awọn anfaani to n ṣe fun agọ ara.
Ki ni a n pe orogbo?
Orogbo jẹ irugbin pataki lati igbo iwọ-oorun Africa to si nii ṣe pupọ pẹlu aṣa wọn.
Wọn maa n lo orogbo fun nkan to pọ nitori awọn anfaani ilera to ni.
Awọn onimọ sayẹnsi ka orogbo kun mọlẹbi ‘Clusiaceae’. Irungbin rẹ gangan to wa ninu eso rẹ ni wọn si maa n lo.
Oriṣiriṣi ọna ni awọn eeyan n gba lo orogbo, to fi mọ ki wọn kuu bi ẹbu ki wọn si maa bu si ohun mimu.
Awọn miran yoo saa ko gbẹ daadaa, wọn yoo gee si wẹwẹ abi ki wọn sọọ di ẹbi lati fi ṣe ẹrọ ibilẹ.
Awọn kan si maa n jẹẹ bẹẹ.
Awọn anfaani to sara loore to wa ninu orogbo
Orogbo ni oniruuru eroja aṣaraloore bii ‘alkaloid’, ‘flavonoid’, ‘tannin’ ati ‘amino acid’. Awọn eroja yii n jẹ ki orogbo o lee ṣe afikun awọn ẹya ara to olugbeja lọwọ arun to si tun maa n daabo bo awọn sẹẹli ara lọwọ ibajẹ.
Orogbo ni eroja ‘caffeine’ ati ‘theobromine’ to jẹ bii oluranlọwọ fun ọkan.
Eyi lo mu ki o le maa ṣe afikun bi ọkan ṣe n sare ṣiṣẹ si, nipa lilanu ati pipade daadaa to n mu ki ọkan o ṣiṣẹ bo ṣe yẹ. Bakan naa ni orogbo n ṣiṣẹ fun ọkan to ba n ṣaarẹ kiko omi ati ẹjẹ jọ laitọ
Irugbin kekere yii kun fun eroja ‘xantine’ ati ‘Vitamin C’ to muu yẹ ni lilo fun aito ẹjẹ ati igba ti ara ba ṣẹṣẹ n mokun.
Wọn lo orogbo lọna ibilẹ lati mu iba walẹ ati bii ororo-itura niwaju ori fun itọju aisan iba.
Awọn kan wipe o wulo fun ẹni ti ko ba lee jẹun. Bakan naa lo tun niwulo fun inu kikun latari bo ṣe maa mu ki inu o ṣe akojọ awọn ohun to nilo lati jẹ ikun o ṣiṣẹ bo ṣe yẹ.
Ti eeyan ba n jẹ orogbo deedee, yoo daabo bo ẹdọ onitọhun.
Eso yii tun ni awọn eroja to n rọ ẹfọri, eyin didun ati ẹfọri tuulu.
Pabanbari rẹ ni pe, orogbo tun ni awọn eroja to le mọkunri ṣe iṣe akọ daadaa.
N jẹ gbogbo eeyan lo le jẹ orogbo?
Bo tilẹ jẹ pe orogbo ti awọn anfaani to pọ, o ṣe pataki kawọn eeyan o mọ pe ajẹju rẹ lee gba oorun loju eyan, o lee fa keeyan o maa ta giri laisi ohun to ṣẹlẹ, o si tun le mu ki ọkan o maa sare asaju ti eeyan o si maa mi gulegule latari eroja ‘caffeine’ to ni.
Nitori idi eyi, ki eeyan o jẹẹ mọ niwọn, ki apọku rẹ o ma baa fi aisan pamọ abi ba ewu de.
O ṣe koko ki awọn eeyan o mọ pe iṣẹ ti orogbo n ṣe lori ọpọlọ atawọn ẹya ara to so mọọ le mu ko di ohun to le lati fi silẹ.
Awọn to ba ni aisan ọgbẹ inun, aisan ọkan, airi orun sun, aya jija abi ẹjẹ riru ko lee jẹ orogbo.
Bakan naa ni ko daa ki obirin o jẹẹ ninu oyun abi nigba ti wọn ba n fun ọmọ lọmu. Bẹẹni ọmọ kekere ko lee jẹẹ.