Mò ń wọlé-jáde láti ilé ìwòsàn, ni kò jẹ kí ń tọjú aya àtàwọn ọmọ mi – Itele

Itele

Oríṣun àwòrán, iteledicon01/Instagram

Gbajugbaja osere tiata lagbo ere Youba, Ibrahim Yekeen, ti ọpọ eeyan mọ si Itele ti fesi lori ọpọ awuyewuye to n lọ nipa rẹ ati idile rẹ.

Ni bii ọsẹ kan sẹyin ni gbajumọ oju opo iroyin kan lori ayelujara pariwo osere tiata naa sita pe ko naani awọn iyawo meji ati ọmọ marun to ti bi saaju.

Itele ni wọn fi ẹsun kan pe o ti fẹ iyawo meji tẹlẹ, iyawo akọkọ lo bi ọmọ meji nigba ti ekeji bi ọmọ mẹta.

Amọ Itele ni wọn fẹsun kan pe o fẹ iyawo miran to n ba lo lọwọ lọwọ bayii, ti onitọun si ti bimọ kan fun eyi to se ikomọjade rẹ, ti aye gbọ, ti ọrun mọ.

Ẹgbẹrun lọna aadọrin naira ni mo maa n fun iyawo mi keji ati ọmọ mẹta:

Nigba ti gbajumọ osere tiata naa n fesi lori awọn ẹsun ti wọn fi kan, lo ba gbe fọnran aworan kan jade nibi to ti n pe iyawo keji naa.

Ninu fọnran naa ni Itele ti n fidi rẹ mulẹ fun obinrin naa pe oun maa n fun ni ẹgbẹrun lọna aadọrin naira losoosu lati setọju awọn ọmọ rẹ mẹtẹẹta.

Amọ lẹyin o rẹyin ni obinrin naa tun kede fun araye pe arumọjẹ lasan ni fidio ti Itele gbe sita nitori kii fun oun ni owo kankan.

Saaju ninu awọn fọnran aworan ti obinrin naa gbe sita lo ti n salaye pe awọn ọmọ oun wa nile, ti wọn si ti le wọn wa sile lati ile ẹkọ nitori pe wọn ko ri owo ile ẹkọ san.

Bakan naa, inu ile tui obinrin naa atawn ọmọ rẹ n gbe ninu fidio naa ni ko wu oju ri, ti asọ ara ati bata awọn ogo wẹẹrẹ naa ko si wu oju ri.

Ọpọ eeyan lo faraya lori iwa ailakasi ẹbi rẹ ti osere tiata naa hu, ti wọn si da owo jọ loju opo iroyin naa lati fi se iranwọ fun iyawo keji Itele to ni awọn ọmọ ko le lọ sile ẹkọ.

Se ni wọn n yọ suti ete si Itele pe bo se gbajumọ to, ki lo de ti ko fi le tọju awọn ọmọ ati aya rẹ to ti ba jiya, ko to di olokiki.

Itele ati awọn ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, iteledicon01/Instagram

Ara mi ko ya lati igba ti mo ti se sinima Kesari – Itele

Amọ nigba to n pada fesi lori isẹlẹ naa, Itele, ẹni to ti foju han pe o kabamọ awn ihuwasi rẹ lati ẹyin wa naa, wa seleri lati iywa pada.

Itele ni kii kuku se pe oun ko fẹ setọju aya atawọn ọmọ oun amọ ojojo n sogun, ara ogun oun ko le, to si rẹ oun diẹ.

Gbajumọ osere tiata naa ni bi oun se n wọle iwosan ni oun n jade nibẹ lati igba ti oun ti gbe sinima Kesari jade ni ọdun mẹta sẹyin.

Itele ati alaye to se soju opo Instagram rẹ

Oríṣun àwòrán, iteledicon01/Instagram

Wọn ta Itele ni ọfa lyin to se sinima Kesari tan – Kemity

Bakan naa ni arabinrin kan to jẹ ọmọ isẹ Itele lagbo tiata, Ariyo Oluwakemisola Apesin, ti ọpọ eeyan mọ si Kemity lori ayelujara sọrọ nipa ohun ti ọga rẹ n la kọja.

Ninu fidio kan to gbe jade, nibi to ti n sunkun kikan, Kemity ni wọn ti ta Itele ni ọfa, ti ko si le fi ẹsẹ rẹ rin daadaa, bẹẹ lo n paara ile iwosan.

Kemity wa leri leka pe ọga oun yoo yipada, ti yoo si maa se ohun to tọ ati eyi to yẹ fawọn ọmọ ati aya rẹ to ti pa ti tẹlẹ.

Itele ati awn ọmọ rẹ nile itaja

Oríṣun àwòrán, iteledicon01/Instagram

Itele yipada lati se atunse, o lọ ra asọ fawọn ọmọ rẹ:

Ohun to wa jẹ ohun iwuri ninu isẹlẹ naa ni pe gbajumọ osere tiata yii mu ileri rẹ sẹ lati yipada, to si ko awọn ọmọ rẹ lọ ibudo itaja ti wọn ti n ta asọ.

Nibẹ lo ti ra ọpọ asọ, bata fawọn ọmọ rẹ naa, ti oun funra rẹ si ko wọn sinu mọto rẹ lati gbe wọn lọ.

Inu ọpọ eeyan to ti n ba isẹlẹ naa bọ, lo dun si ayipada ọtun yii, ti wọn si n pada kan saara si Itele pe o ku ọmọ se nitori bo se yiwa pada naa.