Mo gbé ìgbésẹ̀ láti ṣẹ́ oyún ọmọ mi tuntun, ọkọ mi nàá sì faramọ́ nítorí pé…

Lizzy Anjorin ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Instagram/lizzy anjorin lawal

Gbajugbaja oṣerebinrin to tun ṣẹṣẹ di iya ikoko, Lizzy Anjorin ti sọ oriṣiriṣi iriri to lakọja ṣaaju, ati lasiko to loyun ọmọ rẹ tuntun.

Anjorin to kede ni ọsẹ to kọja pe Ọlọrun ti fi ọmọ tuntun da oun ati ọkọ rẹ lọla, sọ pe ko wu oun lati loyun bo tilẹ jẹ pe oun fẹran ọmọde.

Ninu ọrọ kan to kọ si ori ayelujara Instagram rẹ ni ọjọ Satide, Lizzy sọ pe oun ati ọkọ oun ti fi ẹnu ko lati wa obinrin miran ti yoo ba oun gbe oyun tabi ki oun gba ọmọ tọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ni ṣaaju igbeyawo oun ni awọn mejeeji ti pinnu lati wa ẹni ti yoo ba oun gbe oyun, nitori pe oun bẹru oyun nini.

Ati pe ọjọ ti oun ati ọkọ oun lọ si ileewosan lati sanwo fun ẹnit i yoo ba oun gbe oyun, ni dokita sọ fun oun pe oun ti loyun.

“Nigba ti a de ọdọ dokita, paapaa lati ṣe ayẹwo boya awa mejeeji koju osunwọn fun ‘surrogacy’, ni dokita ba sọ fun mi pe ko si ẹyin kankan ninu ile ọmọ mi.

Ha! Ko si ẹyin kẹ? Nigba wo ni wọn fi ẹyin mi ṣoogun owo, ti mi o mọ?

Ṣugbọn, ko kami lara rara. Wọn kuku ti sọ pe ko si ẹyin, jẹ ki n lọ maa ta ọjọ mi.”

Lizzy sọ pe ọjọ keji ni dokita sọ fun oun pe oun ti loyun.

Ṣebi o yẹ ki idunnu ṣubu lu ayọ ni, rara o. Niṣe ni ironu dori agba kodo fun Lizzy pe kii ṣe oyun lo kan ni ọrọ oun.

ṣugbọn, pẹlu ijo ati ayọ ni ọkọ rẹ, Lawal, fi gba iroyin naa.

Aworan Lizzy ninu oyun

Oríṣun àwòrán, Instagram/lizzy anjorin lawal

Kilo le mu Lizzy banujẹ lori ọrọ oyun to ni?

Nigba to n tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ, Lizzy Anjorin sọ pe oun bẹrẹ si ni ronu idi ti inu ọkọ oun fidun ju ti oun lọ.

O ni ironu yii si ni eṣu gba lati mu ki oun ronu kọja nkan ti Ọlọrun le sẹ.

“Mo bẹrẹ si ni ronu idi ti inu ọkunyin yii fi n dun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Ṣe o fẹ ẹ ba temi jẹ ni?

“Ta a ni yoo ma ba mi polowo awọn ọja ati ilẹ ti mo n ta?

“Ṣe gbogbo nkan yoo dawọ duro fun oṣu mẹsan-an?”

Gbogbo ero yii lo mu ko sọ fun ọkọ rẹ pe oun yoo ṣẹ oyun naa, ki oun si wa ẹni ti yoo ba oun gbe oyun mii.

lizzy Anjorin Lawal

Oríṣun àwòrán, Instagram/lizzy Anjorin Lawal

Ṣe ọkọ rẹ fi ọwọ si i lati ṣẹ oyun?

Anjorin ṣalaye pe ọkọ oun faramọ ipinnu oun niwọn igba to jẹ pe nkan ti oun fẹ niyẹn.

Bẹẹni dokita naa gba lati ṣẹ oyun naa, ṣugbọn…

“Dokita sọ pe oun yoo ṣẹ oyun naa, amọ mo gbọdọ ṣe awọn ayẹwo kan ki n to o ṣe nitori ọjọ ori mi. Eyi ni yoo si sọ ọjọ ti wọn yoo yọ oyun naa.

“Bi ere, bi awada, bayii ni dokita ati ọkọ mi ṣe tan mi titi oyun fi pe oṣu marun-un lara mi.

“Pẹlu ibinu ni mo fi sọ fun dokita pe igba wo gan-an lo fẹ ẹ ṣe e, nitori pe ikun mi ti n yọ sita.

“Niṣe ni dokita sọ fun mi pe oun ko le pa ọmọ, dandan ni fun mi lati gbe oyun naa.”

Lizzy Anjorin ko ti itori igbesẹ dokita dawọ duro ninu akitiyan rẹ lati ṣẹ oyun.

O bẹ ọmọ ọdọ rẹ lati ba a wa oogun iṣẹyun, ṣugbọn iyẹn gba a ni imọran lati jawọ ninu rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Anjorin ṣalaye pe ibẹru iṣẹ ati oṣi to le deba oun ti iṣẹ oun ba duro fun oṣu mẹsan-an nitori oyun lo gba ọkan oun.

O ni oun ranti nkan ti oju oun ri nigba to loyun ọmọ rẹ akọbi ni ọdun mẹrinlelogun sẹyin.

Ati gbogbo bukaata ti oun ni lati gbọ lasiko yii.

Amọ, gbogbo igbiyanju Lizzy lati ṣẹ oyun ọmọ tuntun yii lo ja si ofo, nitori pe ọkọ rẹ n ṣọ , to si pa gbogbo nkan ti lati ma a mojuto iyawo rẹ.

Eyi to pada fi bi ọmọ ni ọsẹ to kọja.