‘Mo fẹ́ẹ̀ yìnbọn pa ìyàwó mi nígbà tí mo gbọ́ pé ọmọ mẹ́ta tó bí fún mi kìí ṣe tèmi’

Nii Odartey Lamptey,

Oríṣun àwòrán, others

Agbabọọlu orilẹede Ghana nigba kan ri, Odartey Lamptey, ti sọ pe iyanlẹnu nla lo jẹ fun oun nigba ti oun mọ pe ọmọ mẹta ti iyawo oun atijọ bi fun oun kii ṣe ti oun.

Ninu ifọrọwerọ kan laipẹ yii ni Lamptey ti sọ pe ọrọ naa dun oun to bẹẹ gẹ ti oun fẹ ṣina ibọn bolẹ fun obinrin naa.

O ni “Ọlọrun ni ko jẹ ki n ṣe ohun to wa ninu mi, bi bẹẹ kọ, boya maa wa ninu ọgba ẹwọn bayii.

Orukọ iyawo agbabọọlu naa ni Ruweida Yakubu, iṣẹ ere ori itage si ni obinrin naa yan laayo ṣaaju igbeyawo wọn.

Lamptey ni o yẹ ki eeyan kọkọ maa ronu jinlẹ ko to gbe igbesẹ lasiko to ba n binu, bi bẹẹ kọ, irufẹ ẹni bẹẹ yoo ba ọpọlọpọ nnkan jẹ.

Ninu ifọrọwerọ kan loju opo YotuTube, Lamptey, to ti fi akoko igba kan gba bọolu fun Anderlecht ati Aston Villa sọ pe oun ti lọ mu ibọn oun lọjọ naa.

Amọ o ni oun tun ero oun pa lẹẹkeji ni ko jẹ ki oun dana ibọn ya obinrin naa lọjọ naa lọhun.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, kii ṣe ohun to rọrun ki ọkunrin gbọ pe ọmọ mẹta ti oun ti n tọju lati inu oyun kii ṣe ọmọ oun.

Ọdun 2013 ni igbeyawo agbabọọlu naa tuka lẹyin ti ayẹwo DNA fihan pe, oun kọ lo ni ọmọ mẹta ti iyawo rẹ bi fun un.

Ogun ọdun ni Lamptey ati Gloria Appiah fi wa papọ gẹgẹ bii tọkọtaya.