Mo dá N700m padà fún oníbáàrà tí kò rí ilẹ̀ gbà lọ́wọ́ Revolution Plus – Odunlade Adekola

À dúpẹ́ lọ́wọ́ Odunlade Adekola fún átilẹ́yìn rẹ pẹ̀lú wá – RevolutionPlus

Aworan

Oríṣun àwòrán, instagram.com/odunomoadekola/

Gbajugbaja oṣere tiata, Odunlade Adekola ti tu kẹkẹ ọrọ lori ipa to ko lori bi ileeṣẹ Revolution Plus ṣe da owo toto ẹẹgbẹgbẹrin milọnu pada fun awọn onibara ti ko ri ilẹ gba lọwọ ileeṣẹ naa.

Adekola sọ eleyi yi nigba to n fesi lori opo ayelujara rẹ, Instagram, lẹyin ti ileeṣẹ naa fi ẹmi imore han si fun isẹ ribi ribi to ṣe fun idagbasoke ati atunto ileeṣẹ ọhun.

O ni inu oun dun bi ileeṣẹ RevolutionPlus ṣe jẹ ki awọn ololufẹ ohun mọ nipa gbogbo igbesẹ to gbe lọsan loru lori isẹlẹ to wa nilẹ pẹlu ileeṣẹ ati awọn onibara wọn.

“Mo fẹ dupẹ lọwọ ileeṣẹ RevolutionPlus fun bi wọn ṣe jẹ ki awọn ololufẹ mi mọ nkanto mo n ṣe lọsan loru lati yanju awọn isoro to wa nilẹ, ati bi a ṣe da owo to ẹẹgbẹgbẹrin milọnu pada fun awọn onibara ilẹ. Mo ni igbagbọ pe gbogbo isoro naa ni yoo di ohun igbagbe lagbara Ọlọrun.”

Saaju ni Ileeṣẹ RevolutionPlus kede lo ayelujara wọn pe awọn dupẹ lọwọ Odunlade Adekola fun aduroti ati atilẹyin rẹ pẹlu Ileeṣẹ naa nigba iṣoro.

Wọn ki fun isẹ takuntakun to n ṣe fun ileeṣẹ RevolutionPlus lati ibi ọdun marun un sẹyin to darapọ mọ wọn.

Bakan na ni Ileeṣẹ naaa ni iwa ọmọlubi ti awọn ni lo jẹ ki awọn da owo toto ẹẹgbẹgbẹrin milọnu pada fun awọn onibara wọn lọdun 2022.

Ilẹeṣẹ naa ni erongba awọn ni lati yanju gbogbo gbese ti awọn jẹ awọn onibara wọn ni lọdun 2023 yii.

Kí ló dé tí Toyin Abraham àtàwọn Amuludun míì fí yari pé àwọn kò bá iléeṣẹ́ tó ń tà ilẹ̀ ṣé mọ?

Aworan

Awọn amuludun kan lorilẹede Naijira ti sọrọ soke nipa ipolowo ọja ilẹ kan ti wọn se tẹlẹ amọ ti wn n ta ko bayii.

Lara awọn amuludun naa la ti ri gbajumọ osere tiata lobinrin, Toyin Abraham ati adẹrinposonu Lawal Michael Nasiru Bolaji, ti ọpọ eeyan mọ si Nasboi,

Awọn amuludun mejeeji yii si lo ti kede pe awọn ko ni nkankan se pẹlu ileeṣẹ kan to n ta ilẹ, Revolution Property mọ.

Ti a ko ba gbagbe, losu keji ọdun 2022 to kọja, ni ọpọ awọn ọmọ Naijiria bọ si ori ayelujara lati sọ ẹdun ọkan wọn lori awọn ilẹ kan ti wọn sanwo rẹ, ṣugbon ti wọn ko ri ilẹ gba.

Awọn onibara ilẹ to n fapa janu naa tun fẹsun kan awọn gbajugbaja osere ati adẹrinpossonu pe awọn lo ba ileeṣẹ to ta ilẹ naa polowo ilẹ ati ile, ki awọn to ra a.

Alaye ree lori idi tawọn eeyan bẹrẹ si fẹnu abuku kan awọn amuludun to n polowo ilẹ lọdun 2023

Awọn to n binu lori ayelujara yii ni pe igbagbọ ti awọn ni ninu awọn gbajumọ yii lawọn ṣe lọ sanwo ilẹ naa.

Lara awọn ti wọn n darukọ ni Toyin Abraham, Odunlade Adekola, Broda Shaggi ati Testimony Jaga.

Ọrọ naa di ohun igbagbe nigba naa, ti ọpọ eeyan si lero pe isẹlẹ naa ti jẹ rodo, lọ ree mu omi amọ to tun pada rugbo soke bayii.

Onibara miran lo tun bọ sita losu kinni ọdun 2023, eyi ti fidio rẹ gba ori ayelujara, to si n fapa janu pe oun ko ri ilẹ oun gba lọwọ ileesẹ to n ta ilẹ naa.

Idi ree ti awọn eeyan se tun bẹrẹ si ni fi ẹnu abuku kan awọn amuludun to n ba ileesẹ to n ta ilẹ naa polowo ọja rẹ.

Wọn wa n fapa janu pe ki lo de tawọn amuludun naa se tẹsiwaju lati maa fa awọn ololufẹ wọn sinu wahala nigba ti wọn ko le fi ogun ileesẹ ti wn n polowo ọja fun gbari.

Aworan

Oríṣun àwòrán, instagram.com/toyin_abraham/

Ipari oṣu January ni adehun emi ati ileesẹ to n ta ilẹ yoo wa sopin, n ko ba se mọ – Toyin Abraham

Boya ipe awọn ololufẹ Toyin Abraham nipa isẹlẹ naa, lo mu ki gbajumọ osere tiata yii bọ sori ayelujara lati se ikede tuntun nipa isẹlẹ naa.

Ninu ikede naa lo ti sọ fun awọn ololufẹ rẹ pe oun ko kọbi ara si ileeṣẹ to n ta ilẹ naa mọ.

O ni oun ko si ni erongba lati tẹsiwaju pẹlu wọn ninu adehun ti wọn buwọlu saaju nidi ipolowo fun ilẹ ati ile tita ti oun n ba wọn se.

Ninu atẹjade kan to gbe soju opo ayelujara Instagram rẹ, Abraham ni ọjọ kọkanlelọgbọn ni iwe adehun toun buwọlu pẹlu ileeṣẹ naa yo wa sopin.

Amọ o salaye pe oun yoo fi igi gun gbogbo ibaṣepọ awọn nitori isẹlẹ naa..

O wa gba adura pe ki Ọlọrun yọ ileeṣẹ naa ninu gbogbo lasigbo ti wọn n la kọja.

“Fun ẹyin ti ẹ ṣe akiyesi, ẹ ma ri pe n ko kọ ibi ara si ileeṣẹ Revolution Plus mọ.

Mọ n sọ fun yin bayi pe to ba di ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kinni ọdun 2023, iwe adehun wa yoo wa sopin.

Nitori adehun mẹnumọ to maa n wa laarin awa mejeeji, n ko ni le sọ awọn fa ki n fa to n waye laarin wa.

Amọ mo fẹ kẹ mọ pe n ko ni ohunkohun se mọ pẹlu ileesẹ abani ta ilẹ ati ile naa.”

Igba keji ree laarin ọdun kan ti Toyin Abraham yoo bọ sita lati sọrọ lori ibaṣepọ rẹ pẹlu ileeṣẹ to n ta ilẹ naa.

Mo ti yọ fọnran ipolowo ilẹ ti mo gbejade kuro lori opo Instagram mi – Nasboi

Aworan

Oríṣun àwòrán, www.instagram.com/iamnasboi/

Bakan naa, Aderinposonu kan, Lawal Michael Nasiru Bolaji, ti ọpọ mọ si Nasboi ti sọrọ soke lori ibaṣepọ rẹ pẹlu ileeṣẹ to n ta ilẹ naa.

Nasboi sọ pe ni kete ti oun ṣe fọnran ipolowo kan fun ileeṣẹ ọhun, to si gbe sori ayelujara rẹ, ni ọpọ awọn ololufẹ rẹ ti n bẹrẹ si ni ma fi atẹjisẹ ransẹ si oun lori bi ileeṣẹ ọhun ṣe lu awon eeyan ni jibiti.

Ninu alaye to ṣe lori opo Instagram rẹ, o ni oun ko mọ nkankan nipa ileeṣẹ naa tabi nkan ti wọn ti ṣe tẹlẹ sugbọn oun tọrọ aforijin lọwọ awọn ololufẹ oun.

“Ileesẹ to n ta ilẹ ati ile naa lo pe mi pe ki ba awọn se ipolowo ọja wọn, mo si ṣe isẹ naa.

N ko mọ nkankan nipa nkan ti wọn ti ṣe tẹlẹ ri rara.

Mo ti yọ fọnran naa kuro loju opo mi nitori n ko fẹ ko ṣe ijamba fun awọn ololufẹ mi rara.

Mo tun wa tọrọ aforijin lọwọ awọn ololufẹ mi to ṣeṣe ki wọn ti gbe igbesẹ lori fọnran ti mo gbe jade na, pe ki wọn ma binu si mi.”

Ki ni awijare ileesẹ to n ta ilẹ naa?

Ni osu kinni ọdun 2022 to kọja, nigba ti irunu awọn onibara bẹrẹ pe awọn ko ri ilẹ gba lọwọ ileesẹ naa lẹyin ti awọn ti san gbogbo owo to yẹ tan.

Ileeṣẹ Revolution Plus Property Development Company Ltd, loju opo Instagram rẹ nigba naa, gbe atẹjade kan sita lati salaye lori awuyewuye to rọ mọ ọrọ ilẹ ati ile naa.

Ileese naa ni oun ti gbe ariwisi awọn onibara oun yẹ wo, ti oun si ri pe ko si ootọ nibẹ.

Bakan naa lo tun ni pẹlu ootọ inu ni oun fi gbe ileeṣẹ naa kalẹ.

Sugbọn lori ariwisi to waye lọdun 2023 yii, ileesẹ naa ko ti fọhun rara.