Mílíọ́nù méje èèyàn ni ìdọ̀tì inú afẹ́fẹ́ “Air polution” ń pa lọ́dọodún – WHO

Air Polution

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ to n ri si eto ilera lagbaye, WHO ti kede pe idoti inu afẹfẹ jẹ ọkan gboogi lara awọn iṣoro to n dojukọ agbaye lasiko yii.

WHO ni ko din ni miliọnu meje eeyan ti ẹmi wọn sọnu lọdọọdun nitori oniruru awọn arun ti idọti inu afẹfẹ n fa.

Air Polution

Oríṣun àwòrán, facebook: U.S. Mission Nigeria

O ni awọn orilẹ-ede ti ko rọwọ họri ni iṣoro naa dojukọ julọ niroti igbẹkẹle wọn ninu epo rọbi gẹgẹ bii ohun amuṣagbara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni lara awọn idọti inu afẹfẹ ni siga mimu ati jijẹ awọn ounjẹ ti ko tọna.

Ṣaaju ni WHO ti kọkọ sọ fun awọn orilẹ-ede mẹ́rìnléláàdọ́wàá (194) lagbaye lati mu adinku ba bi efin ṣe tu jade lawujọ, ki wọn si ṣe awọn ohun to yẹ lati fopin si awọn iṣoro ti ayipada oju ọjọ n mu lọwọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Adari agba ajọ ọhun, Tedros Adhanom Ghebreyesus sọ pe “Ipenija nla ni idọti inu afẹfẹ n mu ba gbogbo orilẹ-ede lagbaye, ṣugbọn awọn orilẹ-ede ti ko ri jajẹ ni iṣoro naa n koju julọ.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Nnkan bii miliọnu meje eeyan lo n ku lọdọdọdun nitori awọn arun ti idọti inu afẹfẹ n fa.”

WHO sọ siwaju si pe awọn arun na le dí idagbasoke ẹdọforo awọn ọmọde lọwọ.

Lara awọn agbalagba ẹwẹ, idọti inu afẹfẹ le fa aisan ọkan, to fi mọ arun rọpa-rọsẹ.