Mi ò ṣetán láti ṣe igbákejì ẹnikẹ́ni – Kwankwaso

Rabiu Kwankwaso àti Peter Obi

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Olùdíje sípò Ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigeria People’s Party , Rabiu Kwankwaso ti ní òun kò le gbà láti ṣe igbákejì sípò Ààrẹ fún olùdíje kankan.

Kwankwaso ní ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP ń lọ sí oko ìparun nìyẹn tí òun bá fi lè ṣe bẹ́ẹ̀.

Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Kano ọ̀hún tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ìpínlẹ̀ Gombe níbi tó ti lọ ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò ní ìpínlẹ̀ náà.

Ó ní gbogbo ìwọ̀nba òkìkí tí ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP ní ni yóò wọ òòkùn tí òun bá gbà láti ṣe igbákejì ààrẹ fún ẹnikẹ́ni.

Ó ní lóòótọ́ ní ẹgbẹ́ òun àti ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ti jọ ń jíròrò lórí bí àwọn yóò ṣe darapọ̀ àmọ́ ohun tó ń fa ìfàsẹ́yìn ni ọ̀rọ̀ ta ni yóò ṣe ààrẹ?, ta ni yóò ṣe igbákejì?

Kwankwaso fi kun pé gbogbo ohun tí àwọn ti dìjọ ń sọ pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ló ń bọ́ sì déédé àyàfi ọ̀rọ̀ ẹni tí yóò gbé àsíá ẹgbẹ́ dání bí olùdíje sípò ààrẹ.

Ó fi kun pé èyí ló fàá tí àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ fi ń rò ó wí pé kí àwọn tẹ̀lé àwọn ìlànà kan bí i wíwo ọjọ́ orí, ipò tí àwọn ti dìmú tẹ́lẹ̀, bí àwọn ṣe ṣiṣẹ́ sí ní ọ́fíìsì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

“Àwọn ènìyàn inú ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party kò ní fẹ́ gbà bẹ́ẹ̀ nítorí wọ́n gbàgbọ́ wí pé ẹkùn gúúsù ló yẹ kí Ààrẹ Nàìjíríà ti wá’.

“Tí mo bá sì gbà láti ṣe igbákejì ààrẹ, ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP ma fọ́ pátápátá nítorí ohun tí a ti gbìn kalẹ̀ láti ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn ni ẹgbẹ́ náà ṣì dúró lé lórí báyìí.”