Mama Rainbow ṣèdárò ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn ọdún 39 tó jáde láyé

Mama Rainbow

Oríṣun àwòrán, Mama Rainbow

Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Idowu Philips, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Mama Rainbow ti ṣedaro ọkọ rẹ lẹyin ọdun mọkandinlogoji to dagbere faye.

Ninu atẹjade kan ti Mama Rainbow fi lede loju opo Instagram rẹ ni agba oṣere tiata naa ti ṣedaro ọhun.

Ninu aworan ọkunrin naa to fi lede lo ti juwe oloogbe ọhun gẹgẹ bii ọkunrin to ṣe e mu yangan saaju iku rẹ.

O ni “Oni lo pe ọdun mọkandinlogoji ti o ti lọ pade ẹlẹda rẹ ọkọ mi Alamu Ayanfe Omo Oroniyi Kunmi.”

Lẹyin naa lo gbadura pe ki oloogbe ọhun ma ṣe gbagbe awọn ọmọ rẹ àti awọn eniyan to fi si silẹ ki ọlọjọ to de.

“Ko rọrun fun mi lati tọju ọmọ marun-un lai si ọkọ”

Ti ẹ ko ba gbagbe, ṣaaju ni Mama Rainbow ti kọkọ ṣalaye ohun ti oju rẹ ri fun BBC Yoruba lẹyin iku ọkọ rẹ ọhun.

Mama Rainbow salaye pe ọdun meji ati aabọ ni ọkọ oun fi se aisan, ko to dagbere faye.

O ni ọjọ nla ni ọjọ Kejilelogun, osu Kinni, ọdun 1984 ti ọkọ oun, Femi Phillips, ti oun naa jẹ osere tiata, jade laye.

O ni nigba to ku, ti wọn si fẹ sin, oun sọ fawọn eeyan to wa nibẹ pe ki wọn sin awọn ọmọ maraarun tawọn bi pẹlu ọkọ oun nitori iya to n bọ.

O ni ni kete ti ọkọ oun ku tan ni isoro ati iya nla nawọ gan oun atawọn ọmọ maraarun ti awọn bi.

“Oju mejeeji gan n tọ ọmọ, ko rọrun, ka to wa sọ pe oju kan soso, wahala naa pọ, iya jẹ mi, mo si gba ọpọ arifin mọra.

Ko rọrun rara lati tọju ọmọ marun-un, mo si ro pe aye ti parẹ ni nigba ti ọkọ mi ku, ipenija nla si lo doju kọ mi.”

Amọ lẹyinorẹyin, ayọ lo pada ja si fun Mama Rainbow gẹgẹ bii alaye to ṣe fun BBC ṣaaju.