Makinde kéde ìgbà tí ayẹyẹ ìfinijoyè Ọba Olakulehin yóò wáyé gẹ́gẹ́ bí Olubadan tuntun

Aworan Ọba Owolabi Olakulehin

Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti kede igba ti Olubadan ti ilẹ Ibadan tuntun, Ọba Owolabi Olakulehin yoo gori oye.

Ṣaaju ni igbimọ afọbajẹ Olubadan ilẹ Ibadan ti kede Ọba Olakulehin gẹgẹ bii Olubadan kẹtalelogoji nilẹ Ibadan.

Gomina ipinlẹ Oyo ṣi fidi rẹ mulẹ pe oun ti tẹwọ gba igbesẹ igbimọ naa lori Ọba Olakulẹhin.

Makinde ko ṣai sọ pe igbesẹ igbimọ afọbajẹ yii lọ lẹsẹẹsẹ bo ti yẹ ko lọ.

Gomina sọrọ yii di mimọ nibi ayẹyẹ isinku Olubadan to waja, Ọba Lekan Balogun, ni papa iṣere Obafemi Awolowo lagbegbe Oke- Ado niluu Ibadan.

Ni oṣu Kẹta ni Kabiyesi naa lọ darapọ mawọn baba nla wọn lajule ọrun lẹni ọdun mọkanlelọgọrin.

‘’Mo ti gba iyansipo Ọba Olakulehin gẹgẹ bi Olubadan tuntun, kete ti ara baba ba ti le daadaa ni wọn yoo gori itẹ Olubadan.

Amọ, a gbọdọ tẹle gbogbo nnkan to ba yẹ ki a ṣe lori ọrọ oye yii.

Ẹwẹ, mo fẹ fi asiko yii ki gbogbo eeyan ku idide, ẹ si tun ku ọrọ eeyan.

Gbogbo wa ni a maa ṣafẹri Olubadan to waja, ṣugbọn ẹ jẹ ki a dunnu wi pe baba gbe igbe aye to dara,’’ Makinde lo sọ bẹẹ.

Igbimọ afọbajẹ ilẹ Ibadan yan Ọba Olakulehin gẹgẹ bi ẹni ti oye Olubadan kan

Aworan Olubadan Owolabi Olakule

Ninu oṣu Kẹrin ọdun 2024 yii ni igbimọ afọbajẹ Olubadn ilẹ Ibadan ti kede Ọba Olakulehin gẹgẹ bii Olubadan ikẹtalelogoji nilẹ Ibadan.

Ni ibi ipade igbimọ Olubadan to waye ninu aafin Olubadan to n bẹ ni agbegbe Ọj’aba, niluu Ibadan ni wọn ti kede Olubadan tuntun naa.

Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan, Oloye Rashidi Ladọja to ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade naa ṣe alaye wi pe awọn ti yan Olubadan tuntun gẹgẹ bii igbimọ afọbajẹ.

O ni ti Gomina ba ti fi ọwọ sii tan, ohun ti o ku naa ni ki wọn da ọjọ ayẹyẹ ifinijoye.

Saaju asiko yii ni ọpọlọpọ awuyewuye ti rọ mọ iyansipo Olubadan ilẹ Ibadan nitori ilera Ọba tuntun naa.

Ọtun Olubadan ti feṣi si ọrọ ti oloye agba Ọba Ajibola sọ pe ara ọba Olakuleyin ti oyẹ olubadan tọ si ko le daadaa.

O sọ pe awọn onimọ nipa eto ilera nikan ni wọn ni anfani lati sọ nipa ilera ẹnikẹni.

Ladoja ni amofin ni ọba Ajibola, ki i ṣe onimọ nipa eto ilera niotori naa ko si ohunkohun to se ara ọba Olakuleyin, koko lara baba le.

O tun fi kun pe ọba Olakuleyin kii ṣe ọmọ ọgbọn ọdun, ẹni to ju ọmọ ọgọrin ọdun lọ ni ko si ṣee ṣe ki ara rẹ da bii ọmọ ogun ọdun.

O ni “arugbo naa ti ṣoge ri ati pe ọmọ ologun ni baba nigba to wa ni ewe, ẹjẹ ka gbagbe wipe ara olubadan ko ya.”

Ọtun Olubada fi kun pe “lati ọdun 1983 ni ọba Olakuleyin ti n gun akasọ yi bọ lati joye olubadan ṣugbọn Ọlọrun nikan lo n fi ọba jẹ.