‘Libya ni mo ti ríi tí ilé ọmọ èèyàn jáde síta tó dà bíì nylon’

“Àwọn èèyàn ń kú lọ́nà tí wọ́n gbé wa gbà lọ sí Libya, ìtọ̀ àti bẹntiróò láwọn èèyàn ń mu gẹ́gẹ́ bí omi”.

Arabinrin yii ti a fi orukọ bo ni aṣiri kẹnu bọ ọrọ fun BBC Yoruba lori nkan ti oju rẹ ri ni orilẹede Libya to lọ lati lọ wa bi aye yoo ṣe dara fun oun ati ẹbi rẹ.

O ni ilẹ Yuroopu gangan ni ẹni ti oun mọ ni yoo mu oun lọ lati lọ tẹsiwaju ninu iṣẹ nọọsi ti o kọ.

“Mo ṣẹṣẹ ṣe “freedom” tan nigba yẹn ni mo dẹ lọ si Eko lati lọ ṣiṣẹ ni ọrẹ mi yẹn sọ pe ti mo ba wa si ọhun, o maa dara fun mi maa dẹ tete rọwọ mu laarin oṣu mẹfa”.

‘Tórí mo lo agídí pé mi ò ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó ní Libya, wọ́n kán ẹsẹ̀ mi, fẹ́ máà bá mi sùn kí n fi san owó àmọ́…’

Arabinrin naa ati ẹbi rẹ

Alaye ti ọrẹ rẹ lọhun sọ fun un ni pe yoo san owo ti wọn na lee lori to fi wa ba wọn ni ilu oyinbo nipa ṣiṣe iṣẹ ti yoo maa gba owo oṣu yoo si maa san gbese tiwọn titi yoo fi tan.

“Mama mi ti pe mi pe ki n maa pada bọ wale nigba taa de Kano tori mo n woye pe ṣe “embassy” ati papakọ ofurufu wa ni ipinlẹ Kano ṣa toripe a pọ gidi gan, ati ọmọde ati agba la wa nibẹ”.

Kekere kọ o, nigba ti ọmọ mi mi “boya t’Ọlọrun ba sọ pe a maa tun rira, mo kan si adura lọsan loru – Iya

Iya aarabinirin naa

Nigba ti iya arabinrin naa da si ọrọ, o ni oun ti kọkọ sọ fun ọmọ oun pe ko fara balẹ sile ko ni suuru pe nkan maa pada dara amọ o ni ọmọ naa n wo laalaa ati itiraka iya lori oun ati ẹgbọn rẹ lo ṣe tẹle ọrẹ lọ si orilẹede Libya.

“Mo sọ fun un pe iran mi o ṣe iṣẹ aṣẹwo ri pe to ba ti ṣe e mo kọ ọ lọmọ niyẹn”.

“Ọlọrun lo yọ mi pe mi o ku nigba ti ọkọ ti a wọ fun oṣu kan lọna danu sinu iyẹpẹ ti ọpọ eeyan ku si. Wọn n mu itọ, bẹntiroo ati bẹẹ bẹẹ lọ”.

O ni nigba ti awọn kọja Saba lọdọ ọkunrin kan lo ti sọ fun oun pe Libya ni awọn wa to si ni ohun maa ṣiṣẹ fun bii ọdun kan ati abọ ni ọkunrin ẹya Ibo kan sọ fun oun pe iṣẹ aṣẹwo ni wọn n ṣe nibi ti awọn wa.

“Igba ti mo yari pe mi o le ṣe iṣẹ aṣẹwo lo kan irin mọ mi lara, o fi aṣọ di mi lẹnu, kii ṣe emi nikan, o ti pa awọn mii taa jọ wa nibẹ