‘Lẹ́yìn tí mo kàwé gboyè, bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ni àìsàn dédé kọlù mí’

Noella

Noella ṣàlàyé fún BBC Africa bí ohun gbogbo ṣe yípadà fun ní ọjọ́ kan tí àìsàn tí kò gbóògùn ṣe kọlùú.

Ohun tí àìsàn náà máa ń ṣe fún òun ni pé kìí jẹ́ kí ohun mọ nǹka tó bá ṣẹlẹ̀ sí òun ní pàtó nítorí òun kò mọ ìyàtọ̀ láàárín ojú ayé àti ríro nǹkan lọ́kàn mọ́.

Àìsàn Bipolar tó ń bámi jà kìí ṣe èyí tí ènìyàn máa ń lo oògùn sí, àìsàn ọpọlọ ló ń bámi jà.

Ó ní àwọn oògùn tí òun ń lò máa ń mú òun sùn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí òun kìí ráyè ṣe iṣẹ́ lọ́sàn-án bó ṣe wu òun.

Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ ènìyan tó ní àìsàn yìí ni kò gbàgbọ́ pé àwọn ni.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí