Lẹ́yìn ogún ọdún, Ooni parí ìjà láàrín Baba Wande àti Tunde Kelani

Aworan Baba Wande ati Tunde Kilani

Oríṣun àwòrán, Adewale Adetoyese

Ija oun aigbọra ẹni ye ọlọdun pipẹ lo ti wa laarin awọn agba osẹre meji ni Naijiria, Alhaji Kareem Adepoju ti ọpọ mọ si Baba Wande ati Tunde Kilani nipa ere sinima, “Ti Oluwa ni ilẹ”

Ooni tilu Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi ti bawọn dasi ọrọ naa, ti wọn si kede sita pe ija naa ti pari.

Ọjọbọ ni Ori Ade naa gbe awọn igbimọ dide lọ si ile Tunde Kilani to wa nilu Abeokuta lati yanju aawọ to ti le logun ọdun to ti wa laarin awọn agba oṣere meejeji ọhun.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Ooni Ogunwusi, Adewale Adetoyese fi lede fun awọn akọroyin, Ooni gbe oṣuba kare fun awọn agba oṣere ọhun fun bi wọn ti n fi iṣẹ wọn gbe aṣa ati ede Yoruba larugẹ lati ibẹrẹ ti ko si pin yinkin titi di asiko yii.

Ọba Ogunwusi tun juwe ara rẹ gẹgẹ bii ọkan lara awọn ololufẹ awọn agba oṣere meji naa.

Ninu lẹta ti Ooni fi lede, o ni “Nigba ti mo n ba awọn eeyan kan sọrọ lori bi a ṣe fẹ lo sinima Ti Oluwa Nin Ile fun eto Aroba ti a fẹ gbe kalẹ ni mo gbọ nipa ede ayede to waye lori iṣẹ yii.

“Inu mi ko dun, mo si n rọ yin gẹgẹ bii Arole gbogbo Oduduwa pe ki ẹ gba alaafia laaye laarin yin.”

O wa rawọ ẹbẹ si wọn lati jẹ ki ọrọ naa pari patapata.

Ki ni esi to tẹnu awọn ẹni ọrọ naa kan jade?

Ninu esi wọn, Alhaji Kareem Adepoju ati Tunde Kilani ti gba lati pari aigbọra ẹniye eyi to jẹyọ lati igba ti sinima Ti Oluwa Nilẹ ti jade, pẹlu ileri lati jẹ ki iṣẹ naa tẹsiwaju.

“Ilu Osogbo ni moti pade Tunde Kilani, ibaṣepọ iṣẹ to lokimi wa laarin wa lati igba ti awa mejeeji ṣi jẹ ọmọ ikọṣẹ nidi ere ṣiṣe, inu mi si dun gidi si bi Arole Oduduwa ti dasi ọrọ wa.

“Mo si dupẹ lọwọ Ọlọrun Allah ti ko jẹ ki ẹnikẹni ninu wa ti ku pẹlu gbogbo iriri wa.

“Ọrẹ mi ni Tunde Kilani, a o si maa tẹsiwaju lati mu ki iṣẹ wa tubọ ni dagbasoke sii lagbo oṣere ati ilẹ Yoruba lapapọ.” Baba Wande lo sọ bẹẹ.

Tunde Kilani naa dahun pe “gbogbo bi awọn eeyan ti n pe fun ki alaafia jọba laarin wa lo tubo n fi mi lọkan balẹ pe iṣẹ ti ṣe silẹ yoo maa fọhun lẹyin ti a ba ti lọ si ibi ti awọn agba n re, nipa bi awọn eeyan nla bii Oonirisa ṣe n mọ riri ipa ti a n ko lagbo oṣere.

“Mo dupẹ gidi lọwọ Ọba Ogunwusi fun idasi wọn, mo ṣeleri atilẹyin mi fun atungbejade sinima “Ti Oluwa Nilẹ” naa.

Nigba to n sọrọ, ẹlomii to sa nibẹ, Oladotun Taylor wa sọ ọrọ iwuri nipa bi awọn agba oṣere mejeeji ti huwa ọmọluabi, pẹlu atọkasi pe baba ni wọn jẹ si oun, ati wipe igbesẹ ti wọn gbe naa ni yoo jẹ arikọgbọn fun awọn to ṣẹṣẹ n goke bọ lagbo oṣere.

Ti ẹ ko ba gbagbe pe lọdun 1993 ni wọn ṣe agbejade sinma agbelewo “Ti Oluwa Nilẹ” lati ile iṣẹ Tunde Kilani eyi ti Alhaji Kareem Adepoju (Baba Wande) kọ.

Ipele mẹta ọtọọtọ ni wọn fi agbejade sinima naa ṣe, to si jẹ ọkan lara awọn fiimu ti ọwọja rẹ gbalẹ kan an nigba naa.