Lanre Gentry, ọkọ Mercy Aigbe tẹ́lẹ̀ sọ̀rọ̀ sókè lórí ìgbéyàwó aya rẹ̀ àná

Mercy Aigbe

Oríṣun àwòrán, Aigbe/Gentry/Adeoti

Ọkọ gbajugbaja oṣerebinrin Mercy Aigbe tẹlẹ, Lanre Gentry ti sọrọ lẹyin ti Mercy fi oju ọkọ rẹ tuntun lede.

Ọjọ Aiku ni Mercy sọrọ soke lori ere ifẹ oun ati Kazim Adeoti lẹyin to ti kọkọ n fi ọrọ naa pamọ fun awọn ololufẹ rẹ.

Ni kete ti Mercy fi oju Adeoti lede gẹgẹ bii ọkọ rẹ tuntun, ni ọpọ awọn ololufẹ rẹ ti bẹrẹ si n fi erongba wọn sita lori igbesẹ naa, paapaa lori ọkọ rẹ tuntun naa.

Lara awọn to n sọrọ lẹyin ikede Mercy ni ọkọ rẹ atijọ, Lanre Gentry.

Gentry fi fọto kan lede loju opo Instagram rẹ, ti igbagbọ wa pe wọn ya lasiko ti oun ati Mercy ṣi wa papọ gẹgẹ bii tọkọ-taya.

Mercy Aigbe

Oríṣun àwòrán, Lanre Gentry

Ninu fọto ọhun ni a ti ri Mercy Aigbe, Lanre Gentry, Kazim Adeoti ati obinrin kan ti ọpọ eeyan gbagbọ pe oun ni aya Adeoti atijọ.

Akọle ti Gentry fi si abẹ fọto naa ni “Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe otitọ ọrọ ti tu sita… ogo ni fun Ọlọrun.”

Ninu aworan yii si lo ti foju han pe ọrẹ ni Lanre Gentry ati Mercy Aigbe jẹ si Kazzim Adeoti pẹlu iyawo rẹ tẹlẹ, ko to di pe ọrẹ Gentry, eyiun Adeoti pada fẹ iyawo rẹ, tii se Mercy Aigbe.

Aworan naa si ni awọn eeyan ni Gentry ni o n fidi rẹ mul pe Mercy n yan ale mọ oun lara lasiko to wa ninu ile oun, ti otitọ si pada fi oju han sita nibayii ti Mercy ati Adeoti gbẹyin fẹ ara wọn.

Ki lo ṣẹlẹ laarin Mercy ati Gentry ṣaaju?

Ọdun 2017 ni Mery ati Gentry pin gari wọn lori ẹsun ale yiyan ati iwa ipa ninu ile.

Lati ọdun naa lọhun ni awọn mejeji ti maa n sọko ọrọ sira wọn lori ayelujara.

Ninu oṣu Kẹfa ọdun to kọja ni wọn tahun sira wọn lori ayelujara lori ọrọ kan ti Mercy kọ lọjọ naa to jẹ ajọyọ ọjọ awọn baba lagbaye, iyẹn Father’s Day.

Ninu ọrọ naa ni Mercy ti kede pe oun ni oun n se bii Baba ati Iya fun ọmọ oun to ni aba laye, kia naa si ni ọkọ rẹ atijọ fesi pada.

Ikede Mercy pe oun ti ba ọkunrin mii lọ yii lo waye lẹyin nnkan bi oṣu mẹrin ti Gentry naa ti kọkọ kede pe oun ti gbe ẹlomiran niyawo.

Ta lo ni ọmọ ti Mercy bi fun Gentry ki wọn to pinya?

Ọrọ lori ojulowo baba ọmọ naa jẹyọ lẹyin ti okunrin kan sọ loju opo Twitter pe ọmọ naa jọ ọkọ Mercy tuntun, iyẹn Kazim Adeoti, bo tilẹ jẹ pe Lanre Gentry lo bi ọmọ naa fun.

Ọrọ naa ti mu ki ọpọ awọn eeyan maa sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ pe kii ṣe Gentry lo ni ọmọ ọhun.

Mercy Aigbe

Oríṣun àwòrán, @emmaikumeh

Amọ Gentry ti wa sọ loju opo Instagram rẹ pe ọmọ oun ni ọmọ naa, oun ko si fi awọn ọmọ oun ṣere rara.

O ni “Mo dupẹ lọwọ gbogbo ẹyin ti ẹ n sọrọ ati fun ọrọ iyanju yin nipa ọmọ mi.”

“Ojulowo ọmọ mi ni Olajuwon, mo si nifẹ rẹ pupọpupọ… ko si nnkankan ti yoo ya emi atawọn mi.”

Amọ Lanre Gentry ti sọ pe oun ni ojulowo baba ọmọ ti Mercy bi fun oun ki aarin awọ mejeji to daru.

Amin iyasọtọ kan

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Mercy Aigbe kéde orúkọ tuntun lẹ̀yìn ìgbéyàwó rẹ̀ pẹ̀lú Adekaz

Mercy Aigbe

Oríṣun àwòrán, realmercyaigbe

Oniruuru ẹnu lo ti n kun gbajugbaja oṣerebinrin, Mercy Aigbe bayii lori ayelujara nitori bo se sọrọ soke nipa orukọ rẹ tuntun to n jẹ bayii.

Eyii lo waye lẹyin to ṣafihan ọkọ rẹ tuntun, Kazim Adeoti, ti ọpọ eeyan mọ si Adekaz Production.

Mercy, to ti maa n pe ara rẹ ni aya The Owner tẹlẹ, lo ti kọkọ ṣafihan okunrin naa fun gbogbo awọn ololufẹ rẹ, iyẹn lẹyin ti awọn kan ti kọkọ n gbe iroyin kiri pe ere ifẹ wa laarin oun ati ọkunrin naa.

Amọ nigba to ku ọjọ kan ki ọkunirn naa ṣe ọjọ ibi, lo kii ku oriire ọdun tuntun loju opo Instagram rẹ, to si n ki ni mẹsan an mẹwaa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Se Mercy Aigbe ti lọ si Mecca ni, lo se pe ara rẹ ni Alhaja?

Ninu atẹjade kan to fi soju opo Instagram rẹ lọjọ Aje ni Mercy ti pe Adekaz ni Ọba lori aye rẹ.

O ni “Alhaji ati Hajia Kazim Adeoti”

“Mo ṣi n ṣe ajọyọ ọjọ ibi Ọba mi lọwọ!”

“Adura mi ni pe ohun ayọ ni a oo maa ba ọ ṣe titi ọjọ aye rẹ.”

Mercy tẹsiwaju ninu adura naa pe “Mo dupẹ lọwọ rẹ pe o jẹ alaafia fun mi, mo gbadura ki Ọlọrun tubọ maa bukun fun ọ, ko si tun gbe ọ ga ju iwoye rẹ lọ.”

Ọpọ ololufẹ Mercy lori ayelujara lo wa n beere pe se oserebinrin naa ti lọ si Mecca ni, lo se pe ara rẹ ni Alhaja Adeoti?

Ti ẹ ko ba gbagbe, Mercy ti kọkọ fidio ka sita loju Isntagram rẹ, nibi ti olorin Fuji, Wasiu Ayinde Marshal ti n kii, to si n pe aya “the owner.”

Ta ni Kazim Adeoti, Adekaz?

Alhaji Adeoti Kazim ni orukọ ọkọ Mercy tuntun yii amọ orukọ ti ọpọ eeyan mọ ọ si ni Adekaz.

Adekaz yii ni orukọ ileeṣẹ rẹ to n gbe sinima jade, iyẹn Adekaz Production.

Yatọ si eyii, okunrin naa tun ni oludasilẹ ileeṣẹ Ibaka TV, to jẹ ẹrọ ori ayelujara ti awọn eeyan ti n sanwo lati wo sinima.

Ọmọ bibi ilu Orokun nipinlẹ Kwara ni Ọgbẹni Adekaz, amọ ilu Eko ni wọn fi ori rẹ sọlẹ si.

Fasiti ilu Jos lo ti kawe gboye nipa imọ amojuto okoowo.

Ọdun 2002 lo fẹ iyawo rẹ akọkọ, ko to fẹ Mercy Aigbe bayii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ