Kò sọ́rọ̀ mọ́ lẹ́yìn January 31 tówó náírà àtijọ́ yóò di pàǹtí – Emefiele

New Note

Oríṣun àwòrán, Others

 Banki apapọ orilẹ-edeNaijiria (CBN) ti  sọ pe  oun ko ni  fikun ọjọ ti o kede pe opin yoo de ba nina owo naira atijọ.

Ọdun to kọja ni CBN kede owo igba naira, ẹẹdẹgbẹta naira ati ẹgbẹrun kan naira tuntun to si sọ pe ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kini, ọdun 2023 yii ni opin yoo de ba nina awọn  owo naira naa.

 Gomina banki apapọ orilẹ-ede yii (CBN) Godwin Emefiele kede eyi lẹhin ipade Igbimọ awọn alaṣẹ Iṣowo ti banki orilẹ-ede yii (MPC) ni Abuja.

 Godwin Emefielemi ni , iwa ijinigbe ati gbigba  owo itusilẹ ti dinku lati igba ti banki apapọ ti kede iwe-owo mẹta ti tun naa.

O tun sọ pe akoko ti a banki apapọ kede lati paarọ awọn owo naira atijọ pẹlu awọn owo naira tuntun ti to fun awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lati lọ si awọn banki ati lati gba awọn owo naira titun.

Ọpọlọpọ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria  ni wọn ti n sọrọ lori bi won yoo se ri owo naira titun mẹtẹẹta naa gba.

Bẹẹ ni banki apapọ orilẹ-ede yii si ti tẹnumọ pe lẹyin ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kinni ọdun yii ni ohun  ko ni gba owo naira atijọ mo.

 Laipe yii ni CBN paṣẹ ki  awọn banki orilẹ-ede yii  dawo sisan wo titun ninu banki ki wọn si ko won sinu ẹrọ ATM ki itankalẹ owo titun naa le pọ si.

 Banki apapọ orilẹ-ede yii tun ṣe eto lati paarọ owo ki gbogbo awọn to wa ni igberiko le ni ore ọfẹ  lati  paarọ awọn owo ọwọ wọn.

Ile-igbimọ Aṣoju sofin ati Igbimọ awọn Gomina Naijiria ti beere lọwọ CBN lati fa ọjọ naa ṣiwaju lati jẹ ki awọn ọmọ orilẹede Nàìjíríà ri owo tuntun na gba.