Kíni òfin Nàìjíríà sọ lórí bí Gómìnà Akeredolu ti ń ṣèjọba Ondo láti ìlú Ibadan?

Aworan Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi/Facebook

O ti le ni oṣu meji bayii ti gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu pada si orilẹede Naijiria lati oke okun ti o ti lọ gba itọju tori ailera rẹ.

Lati igba to si ti pada de ni o ti wa nilẹ niluu Ibadan nibi ti o ti n ṣe ojuṣe rẹ gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Ondo.

Ọpọ awuyewuye lo ti jẹyọ lori bi Akeredolu ko ṣe tii pada si ilu Akure tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ondo lati igba to ti pada si Naijiria.

Awọn eeyan kan ti sọ wi pe ki o kọwe fipo silẹ nitori ailera rẹ, bakan naa lawọn igbile igbimọ aṣofin naa ti gbiyanju lati yọ nipo.

”Ofin Naijiria ko sọ ohun kohun nipa ibi ti gomina ti le maa ṣe ijọba”

Amofin Jiti Ogunye fidi rẹ mulẹ fun BBC Yoruba pe ofin Naijiria ko sọ ohunkohun nipa ibi ti gomina le wa lati maa ṣe ijọba ipinlẹ rẹ.

Agbẹjọro ọhun wi pe ti gomina ba ṣe aarẹ to si fẹẹ lọ gba itọju ni ofin sọrọ nipa rẹ pe ko kọwe sile aṣofin lati fi to wọn leti ati lati gbe ijọba silẹ fun igbakeji rẹ, ko si tun fi to wọn leti ni kete ti o ba pada lati ibi ti o ti lọ gba itọju.

Ogunye ni“akoko ti Aarẹ ana Naijiria Yaradua ṣe ailera to si lọ gba itọju ọlọjọ pipẹ ni atunṣe de ba ofin pe ki gomina abi aarẹ maa fi to ile aṣofin leti ki wọn si gbe ijọba silẹ fun igbakeji wọn.

Ofin ko ni afojusun pe gomina kan yoo de lati ibi to ti lọ gba itọju ti ko si nii yọju si ipinlẹ to ti o ti n ṣejọba.

Awọn oloṣelu lo maa n ṣe oniruuru idaru to maa n mu kawọn araalu o pe fun atunṣe iwe ofin.

Ohun to n ṣẹlẹ nipinlẹ Ondo lọwọ yii ko ṣẹlẹ ri lorilẹ-ede yii eyi ti ko jẹ ki ofin o ni ipese kalẹ fun irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ.”

”Atilẹyin igbimọ alaṣẹ ipinlẹ Ondo ko ni i ohun kan ṣe pẹlu ofin Naijiria”

Awọn igbimọ alaṣẹ ipinlẹ ṣe atilẹyin fun gomina Akeredolu lẹyin ti wọn dibo pe awọn wa lẹyin rẹ, bo tilẹ jẹ pe meji ninu awọn ọmọ ẹgbẹ igbimọ alaṣẹ ọhun ko fọwọ si ọrọ apilẹkọ ti wọn buwọlu lẹyin ipade wọn.

Agbẹjọro Ogunye ni ko si ohun to buru ninu igbesẹ awọn ọmọ igbimọ iṣejọba ipinlẹ Ondo lati pe wọn ṣe atilẹyin fun gomina to yan wọn sipo amọ eleyi ko ni nkan kan ṣe pẹlu ofin orilẹ-ede Naijiria.

Ogunye ṣalaye pe ofin Naijiria kọ mọ nkan to n jẹ “vote of confidence” gẹgẹ bi awọn igbimọ naa ṣe wi.

Agbẹjọro naa wi pe ohun ti ofin Naijiria mọ, ni ibamu pẹlu abala kọkandinlaadọwa iwe ofin Naijiria ni pe ki igbimọ iṣejọba o jokoo lati boju wo ilera gomina boya o le tẹsiwaju abi ko le tẹsiwaju ati pe afẹnuko ida meji ninu mẹta ni wọn yoo fi ṣọwọ si ile aṣofin lati ṣiṣẹ le lori.

Ogunye ṣalaye pe“i awọn ọmọ ile aṣofin ba ti gba irufẹ abọ ipade igbimọ iṣejọba yii, ohun ti wọn yoo ṣe ni lati gbe igbimọ tẹẹkoto awọn oniṣegun kalẹ lati wo ipo ilera gomina bẹẹ abi igbakeji rẹ.

Ọkan ninu awọn marun ti yoo wa ni igbimọ tẹẹkoto yii gbọdọ jẹ oniṣegun gomina naa ti yoo le fi oju ara rẹ ri gbogbo ayẹwo ti awọn dokita naa ba n ṣe.

Abọ igbimọ tẹẹkoto yii ni yoo sọ boya gomina naa lee tẹsiwaju abi ki wọn yọọ nipo, leyi ti ile aṣofin yoo fi lede ni kia.

Amọ fifi ohun ẹnu ṣe atilẹyin fun gomina lai tẹle ilana ofin ni ko si ni ilana iṣejọba orilẹ-ede yii ṣugbon to jẹ ohun ti awọn oloṣelu lee ṣe lati fi ifẹ han si olori wọn, ti eyi ko si nii ṣe pẹlu ofin abi iṣejọba.

Awọn ilu bii ilẹ Gẹẹsi to n lo ilana oṣelu “parliamentary” ni wọn ti maa n sọrọ nipa “vote of confidence” leyi to yatọ gedengbe si ilana aarẹ apaṣẹ wa “presidential” ti a n lo nilẹ yii.

Ko si ohun to n jẹ “vote of confidence” abi “vote of no confidence” ninu ofin Naijiria amọ wọn ni igbalaaye labẹ ofin lati ṣe ohun to ba wu wọn gẹgẹ bii oloṣelu nitori ara to ba wu wọn ni wọn le da, ti ko si ni ohunkohun ṣe pẹlu ofin.”