Kí ni Ọ̀gágunfẹ̀yìntì Buratai ń ṣe ní Benin Republic, ìlú tí Sunday Igboho ti ń jẹ́jọ́?

Olori ileeṣẹ ọmọogun Naijiria nigba kan ri, Tukur Buratai ti farahan niwaju aarẹ orilẹede Benin Republic, Patirce Talon. Ọjọ Iṣẹgun ni eyi waye nile aarẹ Orilẹede naa.

Bi ẹ ko ba gbagbe orilẹede Benin yii kan naa ni eekan ọmọ Yoruba to n lewaju idasilẹ orilẹede Yoruba, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho wa bayii to ti n jẹjọ lẹyin to fẹ gba orilẹede naa kọja si orilẹede Gernmany.

Amọṣa kii ṣe tori ọrọ Igboho ni Ọgagunfẹyinti Buratai ṣe lọ si ilẹ Benin Republic, Ọgagunfẹyinti Buratai ni aṣoju ijọba orilẹede Naijiria tuntun si orilẹede Benin. Ni ọjọ Iṣẹgun lo si mu iwe aṣẹ lọ fun aarẹ orilẹede naa, Patrice Talon.