
Oríṣun àwòrán, Channels TV
Ede aiyede to waye laarin awọn ẹṣọ ajo EFCC atawọn ọmọ ogun ofurufu ilẹ yii kan ni Kaduna lo ti di ohun to mu kawọn ologun naa o ṣigun lọ ọgba ajọ EFCC.
Gẹgẹ bii fanran ti ileeṣẹ amohunmaworan Channels fi lede, awọn ologun naa lo ya bo ọfiisi ajọ EFCC to wa ni ilu Kaduna ninu ọkọ bii mẹta ti wọn si yi geeti abawọle si ọfiisi naa ka, leyi ti ko jẹ ki ẹnikẹni o lee wọle tabi jade.
Niṣe lawọn ologun naa atawọn ọlọpaa to wa lọfiisi EFCC naa n jagbe mọra wọn bii pe wọn wa loju ogun, ti wọn si n na ibọn sira wọn, amo ko sẹni to yinbọn ninu awọn mejeeji.
Kíni ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an?
Ninu atẹjade kan ti ajọ EFCC fi lede, Dele Oyewale to jẹ adari ẹka iroyin ati ipolongo fun ajọ naa wi pe igbiyanju awọn ọmọ-ogun ofurufu kan lati fipa tu awọn afurasi alujibiti lori ẹrọ ayelujara to wa lagọ ajọ naa silẹ lo fa wahala.
Atẹjade naa ka pe “ni ọjọ Aje, ọjọ kẹtala oṣu kọkanla ọdun 2023 ni awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC ni Kaduna mu awọn afurasi marun nile ounjẹ kan ni agbegbe Barnawa ni Kaduna lẹyin ifimufinlẹ nipa ẹsun lilu jibiti lori ẹrọ ayelujara.
Awọn afurasi naa Favour Itung, Rachael Ande, Zuleiman Haruna, Abubakar Ismaila ati Solomom Olobatoke ni wọn mu lai si aawọ kankan.
Ẹwẹ, lẹyin eyi ni awọn ologun mẹfa to ri bi wọn ṣe mu awọn afurasi naa wa si agọ wa lati waa fipa tu awọn afurasi naa silẹ amọ tawọn ẹṣọ to wa nibẹ kapa wọn, ti wọn si mu wọn silẹ.
Awọn mẹfa naa ni mẹrin ninu wọn n jẹ, Lawal Abdullahi, Chukwuma Chidi Christian, Alfa Suleiman ati Emmanuel Ekwozor jẹ ọmọgun ofurufu, ti orukẹ awọn meji to kun jẹ Chidera Anuba ati Joseph Tokula ti wọn si jẹ akẹkọọ nile ẹkọ ologun ‘Nigerian Air Force Institute of Technology’.”
Níbo ni ọ̀rọ́ dé dúró báyìí?
Oyewale tẹsiwaju ninu atẹjade naa pe “Bi awọn ologun yii ṣe wa ni ihamọ lọdọ wa, asọyepọ ọrọ n lọ laarin awon adari ajọ EFCC ati ati ti ajọ ologun ofurufu lati yanju iṣẹlẹ ọhun.
O ṣeni laanu pe ijiroro yii lo foriṣanpọn lọjọ Ẹti, ọjọ ketadinlogun oṣu kọkanla ọdun 2023 nigba ti awọn kanda inu irẹsi kan ninu awọn ọmọgun ofurufu yabo ọfiisi ajọ EFCC ni Kaduna bii pe wọn n lọ oju ogun ni igbiyanju lati fipa tu awọn akẹgbẹ wọn silẹ.
Awọn oṣiṣẹ wa kora wọn nijanu lai wo iwa kobakungbe ati aṣilo agbara lati ọwọ awọn ologun yii, bẹẹ la tẹsiwaju lati maa ba awọn ọga wọn sọrọ ti a si ti jọwọ awọn ologun naa lẹyin iforukọsilẹ.”
EFCC wa fi da awọn araalu loju pe awọn yoo tẹsiwaju lati maa ṣe iṣẹ wọn bo ṣe tọ nibamu pẹlu ofin lati le pinwọ gbogbo iwa ibajẹ to nii ṣe pẹlu ọrọ-aje ati ikowojẹ lai fi ti idena kankan ṣe.
Ẹwẹ, ajọ ologun ofurufu ni ko tii sọ ohunkohun lori ọrọ naa titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ.