Kí lo fà á tí Iyabo Ojo fi fẹ́ wọ́ Lizzy Anjorin lọ sílé ẹjọ́?

Aworan Iyabo Ojo ati Lizzy Anjorin

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/ALICE IYABO OJO/LIZZYANJORIN

Gbajumọ oṣere tiata nni, Iyabo Ojo ni oun ti ṣetan lati wọ akẹgbe oun miiran, Lizzy Ajorin lọ sile ẹjọ.

O ni ẹsun ibanilorukọjẹ ni oun ẹ gbe lọ sile fun.

Olabimpe Ajegbomogun, to jẹ agbẹjọro fun oṣere tiata naa nigba to n ba BBC News sọró ni diẹ lo ku ki awọn o pari gbogbo eto lati gba ile ẹjọ lọ.

Ajegbomogun ṣalaye pe gẹgẹ bii agbẹjọro fun Iyabo Ojo ni onibaara awọn lo kan awọn pe Lizzy Anjorin n sọrọ odi si oun lori ayelujara ti gbogbo aye si mọ pe oun lo n ba wi.

O ni idi niyi ti awọn fi gbe awọn igbesẹ kan nitori gẹgẹ bi agbẹjọro awọn gbọdọ ni ẹri lati fi idi ẹjọ mulẹ nile ẹjọ ki aọn to gba ile ẹjọ lọ.

Agbẹjọro Iyabo ni “Ni opin ọsẹ, Iyabo ṣe fido kan lati sọ pe ti Lizzy ba laya, ko da orukọ oun, leyi ti Lizzy fesi si pe oun ko nii darukọ rẹ, ati pe ṣẹpẹtẹri ati awọn orukọ to ku ti oun n pee ni oun yoo maa pee.

“Ti awọn alatilẹyin Lizzy ba si n wi pe Iyabo lo n ba wi, ko ni dahun pe Iyabo ni abi Iyabo kọ. Nigba miran, a tun maa kin wọn lẹyin ti wọn ba darukọ Iyabo.”

Ajegbomogun ni nitori Iyabo nikan kọ ni oun ṣe n ṣe eleyi, amọ oun fẹẹ fi opin si idunkoko mọni lori ẹrọ ayelujara ni.

“Eyi lo mu ka kọ iwe sii pe ki o tọrọ aforijin, ki o san owo gba ma binu ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira, ko si yẹra fun sisọ ọrọ kobakungbe nipa onibara wa.

Amọ, kaka ki Lizzy o tẹle awọn alakalẹ yii, niṣe lo tẹsiwaju lati maa bu Iyabo leyi to mu ka pinnu lati wọọ de ile-ẹjọ.”

Kini ohun to fa ọ̀rọ̀ ile-ẹjọ́?

Ni ọjọ Iṣẹgun ni Iyabo Ojo fi atẹjade kan sori ẹrọ Instagram rẹ pe oun fẹ wọ oṣere tiata to tun gbajumọ olokoowo, Lizzy Anjorin lọ sile ẹjọ fẹsun ibanilorukọjẹ.

Iyabo Ojo ninu lẹta ti agbẹjọrọ rẹ kọ ranṣẹ si Lizzy naa ni o n sọ orọ odi soun lori ayelujara leyii to si n ṣakoba fun oun.

O ni bi o tilẹ jẹ pe ko da orukọ oun ni pato, o ni awọn fidio atawọn ọrọ to n kọ soju opo Facebook ati Instagram rẹ n ba oun wi.

O fi kun pe oun ni awọn ẹri lati le fidi rẹ mulẹ pe oun ni Lizzy n ba wi ati pe nigba ti oun ṣe fidio pe ko darukọ oun lo ṣe omiran lati fun oun lesi.

Ohun ti Iyabo Ojo n beere fun ninu iwe naa ni pe ki Lizzy ka gbogbo ohun to sọ nipa oun kuro lori ayelujara rẹ laaarin ọjọ mẹrinla.

Bakan naa lo ni ko tọrọ aforiji, ko si san owo gba mabinu ti iye rẹ jẹ ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira fun gbogbo ohun to ti sọ nipa oun.

O tẹsiwaju pe bi Lizzy ba kọ lati ṣe awọn nnkan ti oun ka silẹ yii laaarin gbedeke ọjọ mẹrinla ti oun fun ni oun maa wọ lọ sile ẹjọ ti oun si maa gba owo itanran biliọnu kan naira lọwọ rẹ.

Iyabo, lakoko to fi iwe naa lede loju opo instagram rẹ lo kọọ pẹlu rẹ pe “ọjọ mẹrinla fẹe pe. Ija n bọ”.

Lizzy Anjorin ni ko ba akọroyin BBC Yoruba sọrọ nigba ti wọn pe ẹrọ ilewọ rẹ, ti ko si tii fesi si atẹjiṣẹ titi di akoko ti a ko iroyin yii jọ.