“Kí ló dé táwọn òṣèrébìnrin fí ń ṣoríire ju àwa ọkùnrin akẹgbẹ́ wọn lọ?”

Aworan

Oríṣun àwòrán, Instagram.com/kunleremiofficial/

Gbajugbaja oṣere tiata, Kunle Remi, ti sọrọ lori idi to fi dabi wi pe awọn oṣere tiata obinrin fi n ṣe daada ju awọn ọkunrin akẹgbẹ wọn lọ.

Kunle, nigba to n sọrọ nibi eto ifọrọwerọ ‘Honest Bunch’ lori ayelujara, ni igba miiran ohun iyalẹnu lo jẹ, ti oun ba de sibi isẹ pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ oun kekere sugbọn ti awọn oṣere tiata obinrin wọle pẹlu ọkọ bọgini olowo iyebuye.

“Mo mọ iye ti wọn san fun mi lori iṣẹ, mo mọ iye owo ti wọn fun awọn akẹgbẹ obinrin, sugbọn ohun to ya ni lẹnu pupọ ni.”

O tẹsiwaju pe ọpọ igba ni awọn oṣere obinrin ma ń sọ pe awọn ni ọpọ ọna ti owo n gba wọle fun àwọn, ti wọn ba bi wọn pe bawo ni wọn ṣe ra ọkọ bọgini olowo nla ra ninu iṣẹ kan naa ti a jọ ń ṣe.

“Igbesi aye to fara pẹ irọ n ṣe ọpọ ijamba fawọn oṣerebinrin to ń dìde bọ”

Kunle ni igbesi aye to fara pẹ irọ yii lo n ṣe ọpọlọpọ ijamba fun awọn oṣere tiata obinrin to ń dìde bọ.

“Ọpọ igbesi aye yìí lo n ṣe ijamba fun awọn obinrin tiata ti wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ darapọ mọ wa nitori wọn ń reti ọpọ nnkan ninu isẹ tiata sugbọn wọn yoo ri ijakunlẹ ti wọn ba ri pe nnkan ko ri ibi wọn ṣe ro o.

“Bi awọn oṣere tiata obinrin ṣe n ṣe daada ju awọn ọkunrin akẹgbẹ wọn lọ, ibeere nla ni.

“Pupọ awọn nnkan yìí lo jẹ ọrọ ẹnu lasan, sugbọn awọn oṣere obinrin kan ti wọn ni ọpọ ọna ti owo gba wọle fun wọn.

“Awọn oṣere tiata kan n ṣe akoba fun awọn to n bọ lẹyin wa pe nnkan lọ daada sugbọn ti awọn naa ba de bẹ, wa ri pe ko si nnkan ni bẹ rara.