Kẹ́kẹ́ Márúwá ni mo wọ̀, ọwọ́ ajínigbé ni mo bọ́ sí tọmọ-tọmọ – Rukayat Sodiq

Rukayat Sodiq ṣàlàyé bí ọmọ ọwọ́ tó gbé dání ṣe kó o yọ lọ́wọ́ ajínigbé nínú kẹ̀kẹ́ Márúwá

Aworan

Obinrin kan, Sodiq Rukayat ti salaye bi o ṣe ko sọwọ awọn ajinigbe ni agbegbe Igando nipinlẹ Eko.

 Rukayat, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni oun jade kuro nile lati lọ gba abẹrẹ ajẹsara fun ọmọ oun nile iwosan kan ni agbegbe Igando.

O ni oun da ọlọkada kan duro lati gbe oun lọ si ile iwosan naa amọ ti ọlọkada naa ni ọna oun ko gba ibẹ lọ.

Obinrin naa ni bi ọkada ṣe lọ bayi ni kẹkẹ Maruwa wa si ẹgbẹ oun, to si ni pe ki oun wọle.

“Bi mo ṣe wọle sinu Maruwa ni iye mi lọ, ti n ko si ranti nkankan mọ.

Awa mẹta ni a wa ninu Maruwa naa.”

“Ajinigbe ni ki n si ibori mi, gba ọmọ lọwọ mi, wọn tun gba ẹsọ ara mi”

Rukayat tẹsiwaju pe “Awọn de si ibi kan, wọn ni ki awa mẹta pẹlu ọmọ bọ si inu ọkọ akero, ti wọn ma fi n na Iyana Ipaja yẹn.

“Ero mẹta lo ku ti bọọsi akero naa yoo fi kun, ti awa mẹta ti a wa ninu Maruwa si darapọ mọ, ti a si bẹrẹ irinajo ọhun.”

Rukayat ni gbogbo awọn ero to wa ninu bọọsi naa ni wọn ko sọrọ, ti awọn miiran si ti sun lọ sinu ọkọ naa.

O ni ko pẹ si igba naa ni ọmọ oun, ti oun n gbe lọ si ile iwosan bẹrẹ si ni ke, to si pariwo gidi gan.

“Bi a ṣe wọ inu ọkọ naa, wọn ni ki n si ibori mi, ki n si bọ awọn ẹsọ to wa lara mi fun awọn, ti wọn si tun gba ọmọ lọwọ mi”

“Obinrin to wa lara wọn ri asọ bọ ọmọ mi lẹnu, ko le dẹkun igbe kike”

Rukayat wa tẹsiwaju pe “Eyi obinrin to wa lara wọn lo gba ọmọ lọwọ mi, o ri asọ bọ ọmọ ẹnu.

Sugbọn ọmọ naa ko dẹkun igbe kike, wọn wa fi nkan bo lẹnu sugbọn ọmọ naa ko gba rara.”

Rukayah tẹsiwaju pe kete ti awọn wọ inu ọkọ ọhun, ni wọn ti gba ẹrọ ibanisọrọ oun ati awọn dukia mii lọwọ rẹ.

O ni awọn afurasi ajinigbe naa ni awọn yoo fun oun ni ẹrọ ibanisọrọ naa pada lati fi pe awọn araale ati mọlẹbi rẹ pe oun ti lọ.

“Ọmọ mi ko dẹkun igbe kike pẹlu bii wọn ṣe fi asọ si lẹnu.

“Nigba ti igbe ọmọ mi pọju, dirẹba ọkọ naa ni ki wọn ja emi ati ọmọ mi silẹ, ka ma baa ṣe akoba fawọn”

Igba meji ọtọtọ ni mo beere pe ki wọn ba mi gbe ọmọ mi, ti obinrin arin wọn si ni ki n fo wa gbe, to si mu ada dani.

“O ni ki n sọ fun ọmọ mi pe ko dakẹ igbe, ti n ko ba fẹ ki wọn fi ada sa wẹlẹwẹlẹ.

N ko le ṣe nkankan sugbọn gbogbo ọrọ ti wọn sọ ni mo n gbọ.

”Nigba ti igbe ọmọ mi pọju, dirẹba ọkọ naa ni ki wọn ja emi ati ọmọ mi silẹ, ka ba ma ṣe akoba fun wọn pẹlu bo ṣe n pariwo di wọn lọwọ.

“Kete ti wọn ja mi silẹ, wọn fun mi ni ọgọrun un naira ki n fi ra kaadi pe awọn mọlẹbi mi.

Nigba to mo beere kiri pe nibo ni mo wa, ni wọn sọ fun mi pe Mile 2 ni wọn ja mi si.”

“Ọlọpaa ni ki n mu ẹgbẹrun mẹta naira wa, ki awọn to bẹrẹ iwadii lori isẹlẹ naa”

Rukayat tẹsiwaju ninu alaye rẹ pe “nigba ti ori ko oun yọ, oun gbiyanju lati lọ fi isẹlẹ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti.

Sugbọn obinrin naa ni fun iyalẹnu oun, awọn osisẹ ọlọpaa naa ni ki oun lọ mu ẹgbẹrun mẹta naira wa, ki wọn to bẹrẹ iwadii lori isẹlẹ naa.

“Nigba ti mo sọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, wọn ni awọn yoo bẹrẹ iwadi sugbọn ki n mu ẹgbẹrun mẹta naira wa lati fi bẹrẹ iwadii.

“Mo sọ fun wọn pe n ko lowo lọwọ lati fun wọn, wọn si ni pe ko si nkankan ti awọn le ṣe, pe ki ma lọ.”

Ki ni Ileeṣẹ Ọlọpaa sọ lori ẹsun yii?

Nigba ti ileeṣẹ BBC Yoruba kan si agọ Ọlọpaa ti obinrin naa fẹsun kan, Ọga ọlọpaa fun agọ ọlọpaa to wa ni igando, Yerima Mattew ba wa sọrọ lori foonu.

O ni oun ko le fidi ọrọ naa mulẹ nitori pe oun ko gbọ nipa rẹ rara.

Yerima ni oun maa n wa ni agọ ọlọpaa naa loorekoore, to si jẹ ohun iyalẹnu pe iru nnkan bayẹn waye, eyi to ni o ṣeeṣe ko jẹ pe ko waye rara.

“Irọ to jinna si otitọ ni, mo wa ni agọ Ọlọpaa looorekore, mo ni ẹrọ CCTV ni ọfisi mi.

“Ti nkan bayẹn ba sẹlẹ, ko si bi n ko ṣe ni mọ nipa rẹ.”