Ìyàwó tuntun gé nǹkan ọkùnrin ọkọ rẹ̀ ní Kaduna

Aworan tọkọ-taya ti wọn di ara wọn lọwọ mu

Oríṣun àwòrán, Others

Iyawo tuntun kan, Habiba Ibrahim, ni wọn lo ki ọbẹ mọlẹ to si ge nnkan ọmọkunrin ọkọ rẹ lasiko ti ọkunrin naa, Salisu Idris, n sun lọwọ.

Ki lo le mu iyawo aṣẹṣẹgbe ge ‘kinni’ ọkọ rẹ danu ni ibeere ti ọpọ eeyan to gbọ nipa iṣẹlẹ to waye lagbegbe Kudan, nipinlẹ Kaduna, n bi ara wọn.

Gẹgẹ bi a ti gbọ, oṣu kẹrin ree ti Salisu gbe Habiba niyawo, ko si jọ pe ija kankan waye laarin wọn latigba naa.

Ṣugbọn lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu karun-un ọdun 2024 yii, Habiba ki ọbẹ mọlẹ, o si ge ‘kinni’ ọkọ rẹ fẹu.

Àwọn ará ilé ṣàlàyé ohun tí wọ́n mọ̀

Gẹgẹ bi ohun ti awọn alajọgbele awọn tọkọ-taya Salisu sọ, wọn ni owurọ kutu ọjọ naa ni Salisu pariwo wa lati oju oorun.

Wọn ṣalaye pe ọkọ iyawo naa ṣẹṣẹ ti mọṣalaaṣi to ti lọọ kirun aarọ de ni, o si féyin lelẹ lati sun pada.

Oju oorun naa ni wọn lo wa ti iyawo rẹ fi ki ọbẹ mọlẹ to si ge ‘kinní’ ọkọ.

Ariwo Salisu, ọkọ iyawo tuntun ti wọn gbọ ni wọn lo gbe awọn de ile wọn.

Wọn sare gbe e lọ sileewosan to wa nitosi, lati ibẹ ni wọn ti taari rẹ si ileewosan ijọba apapọ to wa ni Makarfi.

Lati Makarfi ni wọn ti gbe e lọ si ileewosan ẹkọṣẹ iṣẹgun oyinbo Ahmadu Bello to wa ni Zaria.

Ipò wo ni ọkùnrin náà wà báyìí?

Lasiko ti a n kọ iroyin yii, awọn dokita ṣi n gbiyanju lati doola ẹmi Salisu.

Wọn ni ipo ẹlẹgẹ lọkunrin naa wa.

Iroyin ṣalaye pe Salisu naa sọrọ nipo ailera to wa.

Wọn lo sọ pe ohun to jẹ oun logun bayii ni alaafia, oun ko ronu nipa igbeyawo mọ.

Salisu loun ko mọ idi kankan ti iyawo oun fi ge nnkan ọkunrin oun, o lawọn ko ja tẹlẹ rara.

Ṣaa, Habiba to ge kinni ọkọ ẹ ti wa lahaamọ ọlọpaa, o n ran wọn lọwọ ninu iwadii wọn.

Awọn obi iyawo naa si lawọn ṣetan lati sanwo itọju ọkọ ọmọ awọn to n jẹrora lọwọ.