Ìyàwó Adeboye gbàdúrà fún Nàìjíríà ní ìgbà akọkọ tó fara hàn lẹ́yìn ikú ọmọ wọn, Dare

Aworan Pasitọ Dare Adeboye ati iya rẹ

Oríṣun àwòrán, RCCG

Lẹyin iku ọmọ wọn, Pasitọ Dare Adeboye, iyawo oludari ijọ Redeemed Christian Church of God, Folu Adeboye ti farahan fun igba akọkọ to si n fi ẹdun ọkan han si Ọlọrun.

Amọ iyalẹnu lo jẹ pe ẹdun ọkan nipa orilẹede Naijiria lo n fihan kii ṣe ni ti didaro ọmọ wọn to lọ rara.

Iyaafin Adeboye to n dari adura fun orilẹede gẹgẹ bi Iya ni Israẹli gbogbo ijọ RCCG to ṣe maa n ṣe ni gbogbo ipade adura oloṣooṣu ijọ naa ni “ara ọtọ la o fi gbadura lonii”.

Iyawo Pasitọ Adeboye ni isin ọjọ keje oṣu karun ọdun 2021

Oríṣun àwòrán, RCCG

Ṣe ni oju rẹ dan to fa ni mọra bo ṣe ni “ki ẹnikan ko ke Halleluyah o” lede ọkọ rẹ ti gbogbo eeyan mọ ọ fun.

“Adura toni yoo yatọ nitoripe gbogbo saa ati akoko lo ni idi tirẹ, asiko ti a wa ni Naijiria lọwọlọwọ le koko tori pe a wa labẹ igbekun ọta pẹlu iṣoro abo”.

Iyawo Pasitọ Adeboye gbadura kikan fun awọn olori Naijiria to wa ni ijọba pe ki Ọlọrun dari ẹṣẹ wọn ji wọn ko si fi if araalu si wọn lọkan ati ibẹru Ọlọrun.

O sọ ninu adura pe ki Ọlọrun ran iranwọ si Naijiria tori ko si abo fun awọn ọmọ, idile ati orilẹede.

Pasitọ Adeboye ni isin ọjọ keje oṣu karun ọdun 2021

Oríṣun àwòrán, RCCG

Ninu isin ọjọ yii kan naa ni oludari ijọ RCCG naa ti sọ ninu iwaasu rẹ ti oju rẹ ti kun fun ayọ ati idunu si ohun ti o n ṣe pe ayọ ati alafia latọrunwa nikan lo lee pẹ kii ṣe eyi ti awọn nkan aye lee fun eeyan ti yoo tun pada sinu iṣoro.

Lori ọrọ Coronavirus, Pasitọ Adeboye ni ki awọn onigbagbọ ma gbagbọ ninu awọn kan to n sọ pe iṣẹ ọpọlọ ati ọgbọn ori awn ni awn fi ṣgun arun Covid-19 pe irọ gbaa ni ati pe iṣẹgun Covid-19 wa toripe awọn eeyan gbadura ni to si ni awọn iṣoro mii wa ni Naijiria, o gbadura pe iṣi kẹta arun Coronavirus ko ni wọ Naijiria.

Ko tii rekọja ọsẹ ti ọmọ wọn Pasitọ Dare Adeboye dagbere faye ni Pasitọ Adeboye ati iyawo rẹ ti bẹrẹ si ni waasu pada.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ