Ìyá Funke Akindele dágbéré fáyé

Funke Akinde

Oríṣun àwòrán, Others

Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà nnì, Funke Akindele ti pàdánù ìyá rẹ̀, DR R. B.Adebanjo-Akindele.

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Keje, oṣù Kejì ọdún 2023 ni màmá náà mí mímí ìkẹyìn.

Àtẹ̀jáde kan tí ẹ̀gbọ́n Funke Akindele, Olubunmi Akindele fi léde lójú òpó Instagram rẹ̀ ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà ba àwọn lọ́kàn jẹ́.

Ó ní “pẹ̀lú ìpòruru ọkàn, àmọ́ gbígba ohun tí Ọlọ́run kọ ni ìdílé Adebanjo àti Akindele fi kéde ikú ọmọ wọn, ìyá àti ìyáìyá, DR R. B.Adebanjo-Akindele èyí tó wáyé ní ọjọ́ Keje o’sù Kejì, ọdún 2023.”

Ó gbàdúrà kí Ọlọ́run tẹ́ màmá sí afẹ́fẹ́ rere tò sí ní àwọn máa fi bí ètò ìsìnkú gbogbo yóò ṣe lọ léde tó bá yá.