Ìtàn ayé ọ̀gágun Paul-Henri Sandaogo Damiba tó léwájú ológun gbàjọba Burkina Faso?

Aworan ọmọ ogun to n kede igbajọba

Oríṣun àwòrán, Reuters

Lọjọ Aje yii ni awọn ọmọogun lorilẹede Burkina Faso kede pe awọn ti gba ijọba.

Atẹjade ti wọn fi sita lọjọ Isẹgun ti kede ọgagun Paul-Henri Sandaogo Damiba gẹgẹ bi olori ijọba ologun to gbakoso eto ilẹ naa.

Ikede yii waye lẹyin ọjọ mẹta iwọde lati fi ẹhonu han lori bi ijọba ko ṣe kapa awọn agbesunmọmi to n da omi alaafia ilu ru.

Ta wa ni ọgagun yi ati pe ki ni nkan to yẹ ki a mọ nipa rẹ.

Lieutenant-Colonel Paul-Henri Sandaogo Damiba

Ọgagun Paul-Henri Sandaogo Damiba la gbọ pe o yẹ aga nidi aarẹ Roch Marc Kabore.

O kawe gboye ni ile ẹkọ ologun to wa ni Paris gẹgẹ bi Reuters ṣe sọ koda o kawe gboye giga ninu imọ iwa ọdaran.

Ọgagun yi jẹ ẹni ọdun mọkanlelogoji to si ti figba kan jẹ olori ẹka ologun eleyi to n mojuto agbegbe olu ilu ilẹ naa, Ougadougou.

Loṣu Kejila ọdun 2021 ni aarẹ Kabore gbe ipo yii le lọwọ ninu igbesẹ tawọn onwoye sọ pe o jẹ ọna lati ni atilẹyin awọn ologun.

Ọgagun Damiba fi igba kan jẹ ọkan lara awọn ikọ to n sọ aarẹ tẹlẹ, Blaise Compaore titi di ọdun 2011 ti wọn yọ kuro lori ipo.

Onkọwe ni Damiba jẹ, to si ti jẹri ri niwaju adajọ lori awọn to ditẹ gbajọba

Ni ọdun 2019 wọn ke si Damiba lati wa jẹri niwaju adajọ lori awọn to gbimọran lati gba ijọba ṣugbọn ti ko kẹsẹjari lọdun 2015.

Ni ọdun 2016, o lewaju awọn ọmọ ogun ilẹ naa to n koju awọn agbesunmọmi.

Ko fẹ ẹ si ijade awọn ologun kankan ti ko kopa ninu rẹ, to si kọ iwe to da lori igbesunmọmi nilẹ Afrika.

Oun lo jẹ olori awọn ikọ ologun lawọn agbegbe to fi mọ Dori ati Ouahigouya, agbegbe ti ikọlu ti n waye lemọlemọ nilẹ Burkina Faso.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ