Iléẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ Baba Ijesha di oṣu kẹ́jọ lẹ́yìn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá ọmọ́débìnrin tọ́rọ̀ kàn lẹ́nuwò

Inu ile ẹjọ

Ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ aṣemaṣe pẹlu ọmọ kekere ti wọn fi kan gbajumọ oṣere sinima Yoruba, Lanre Omiyinka ti ọpọ mọ si Baba Ijesha ti sun igbẹjs lori ẹjọ naa si ọjọ kọkanla ati ati ikejila oṣu kẹjọ ọdun 2021.

Ninu ile ẹjọ loni, ọmọdebinrin ti ijọba ipinlẹ Eko n pẹjọ pe Baba Ijẹṣa hu iwa aṣemaṣe pẹlu wa nile ẹjọ ti ile ẹjọ si gbọ ti ẹnu rẹ ni idakọnkọ lẹyin ti adajọ ni ki gbogbo awọn ero ati akọroyin to wa ninu ile ẹjọ naa o jade.

Bakan naa ni ikọ agbẹjọro fun Baba Ijẹsha tun ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun Princess to jẹ alagbatọ ọmọdebinrin naa.

Amofin Kayọde Ọlabiran ṣalaye fun awọn oniroyin pe wọn ko tii fi ọrọ wa Baba Ijesha lẹnu wo ninu ile ẹjọ naa bayii.

Baba Ijẹṣa, Princess to jẹ alagbatọ ọmọdebinrin naa ati ọmọdebinrin ti ọrọ kan ni wọn wa ni ile ẹjọ naa loni.

Baba Ijesha: Wọ́n gbé ọmọdé kan wá sílé ẹjọ́ kó wá jẹ́rìí sí ẹ̀sùn Baba Ijesha àti Princess

Princess ati Baba Ijesha

Nibi igbẹjọ gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba, Olanrewaju Omiyinka ti ọpọ mọ si Baba Ijesha, adajọ ti gba pe ki ọmọde kan wa jẹri.

Igbẹjọ naa lo n waye ni ile ẹjọ ti wọn ti n gbọ ẹsun aṣemaṣe to lu mọ ibalopọ nilu Eko.

Amọ ṣe ni adajọ le gbogbo awọn to wa nikalẹ nile ẹjọ sita tori pe o ni ni ibamu pẹlu ofin, ero ko le wa nibẹ bi ẹlẹri to jẹ ọmọde ba wa jẹri.

Ọmọde naa ni wọn ni o ni ohun to lee sọ si iṣẹlẹ to waye yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awọn alatilẹyin Baba Ijesha ati Princess Damilola ti tete de si agbegbe ile ẹjọ lati nkan bii ago mẹsan-abọ owurọ.

Lọjọ Aje ni adajọ Oluwatoyin Taiwo sun igbẹjọ naa siwaju lẹyin ti olupẹjọ, oṣere Princess Commedienne ti orukọ rẹ n jẹ Adekola Adekanye kọkọ ṣalaye ẹjọ tirẹ to lodi si ti oṣere akẹgbẹ rẹ to fẹsun kan.

Princess

Baba Ijesha ti wọn fi ẹsun mẹfa ọtọọtọ kan lara eyi ti ifipa bani lopọ, fifi ipa fi nkan ọmọkunrin wọ ara obinrin, aṣemaṣe pẹlu ọmọde ati bẹẹ lọ gbogbo eyi ti wọn ni o lodi si abala ofin 259, 135, 261 iwe ofin ipinlẹ Eko ọdun 2011 ati abala 135, 263, 262 ti ofin ipinlẹ Eko ti ọdun 2015.

Aworan Iyabo Ojo, Ymi Fabiyi pẹlu Baba Ijẹsha

Oríṣun àwòrán, others

Kí ló mú kí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko fẹ́ kí adájọ́ fòfin de Yomi Fabiyi nílé ẹjọ́?

Ijọba ipinlẹ Eko rọ ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ Baba Ijẹsha lori ẹsun aṣemaṣe pẹlu ọmọdebinrin kan pe ko fofin de gbajumọ oṣere tiata Yoruba ni, Yọmi Fabiyi pe ko gbọdọ wọ ile ẹjọ naa mọ.

Agbẹjọro fun ijọba lori ẹjọ naa, Amofin Olayinka Adeyẹmi ni Yọmi fabiyi ti huwa kini ile ẹjọ yoo ṣe pẹlu sinima tuntun rẹ ‘Ọkọ Iyabọ’ to gbe jade.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ sinama naa da lori igbẹjọ ile ẹjọ naa to waye lọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹfa ọdun 2021 lẹyin ti adajọ ile ẹjọ naa ti paṣẹ pe ki ẹnikẹni o dakẹ ọrọ lori ikanni gbogbo nipa ẹjọ naa.

Ọkan gboogi lara awọn oṣere to gbohun soke lẹyin Baba Ijẹsa ni Yọmi Fabiyi lati igba ti ọrọ ẹsun aṣemaṣe naa ti bẹrẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Agbẹjọro Ijọba ipinlẹ Eko naa ṣalaye fun ile ẹjọ pe gbogbo awọn ọrọ to nii ṣe pẹlu igbẹjọ naa ni Yọmi Fabiyi fi sinu sinama tuntun to ṣẹṣẹ gbe jade naa leyi to ni o tapa si ofin ibọwọ fun ileẹjọ.

Amọṣa agbẹjọro fun Baba Ijẹṣa, Amofin Dada Awoṣika SAN ṣalaye pe ọrọ ko ri bẹẹ rara nitoripe ki igbẹjọ naa to bẹrẹ ni Yọmi Fabiyi ti bẹrẹ iṣẹ lori sinima naa.

Amofin Awoṣika ni oun pẹlu ti wo sinima naa ko si si sna kan to fi gba tako aṣẹ adajọ ile ẹjọ naa.

Ninu ọrọ rẹ, Onidajọ Oluwatoyin Taiwo to n gbọ ẹjọ naa beere boya Yọmi Fabiyi wa ninu ile ẹjọ naa ti wọn si daa lohun pe rara.

Nigba ti agbẹjọro ijọba ni o ṣeeṣe ki awọn aṣoju rẹ o wa nibẹ lati ṣoju rẹ, Onidajọ Taiwo ni ko si bi ile ẹjọ ṣe lee mọ ẹni to wa ṣoju rẹ nile ẹjọ niwọn igba ti ko si ẹnikẹni to kọọ siwaju ori pe awọn n ṣoju fun un.

Ilé ẹjọ́ nílùú Eko ti sún ìgbẹ́jọ́ Baba Ijesha sí ọ̀la Ọjọ́ Iṣẹ́gun, wo ohun tó ṣẹlẹ̀

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ile ẹjọ to n gbẹjọ osẹre tiata Yoruba, James Omiyinka ti ọpọ mọ si Baba Ijesha ti sun igbẹjọ siwaju.

Adajọ Oluwatoyin Taiwo sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹtadinlogun oṣu keje ọdun 2021 yii.

Ẹsun ifipabanilopọ lo wa ni ile ẹjọ ti wọn fi kan Baba Ijesha.

Ẹwẹ, adẹrinpoṣonu, Gbenga Adeyinka ba BBC Yoruba sọrọ pe ododo gbọdọ fi oju han lori ọrọ Baba Ijesha.

Adeyinka ni ẹlẹṣẹ ko gbọdọ lọ lai jiya ẹṣẹ rẹ lori ọrọ to wa nilẹ yii.

Oṣere akẹgbẹ rẹ to n tii lẹyin lati ọjọ yii, Yomi Fabiyi ko farahan nile ẹjọ tori ko si ni orilẹede Naijiria lati igba ti ẹgbẹ awọn oṣere TAMPAN ti pee fun ẹjọ ti ko si yọju.

Lara awọn to peju si ile ẹjọ ni gbajugbaja oṣerebinrin to n ti Princess, iya ọmọ ti wọn ni baba Ijesha fẹ fipa ba lopọ lẹyin, Iyabo Ojo amọ o kọ lati ba awọn oniroyin sọrọ.

Bakan naa, awọn mọlẹbi Baba ijesha bii aburo rẹ ati iya iyawo rẹ ṣi duro gba gba tii lẹyin lai mira ti wọn si wa nile ẹjọ.

A o maa mu ẹkunrẹrẹ wa fun un yin.