Iléẹjọ́ pàṣẹ fún orílẹ̀èdè Benin kó san ₦70.8m fún Sunday Igboho lórí ìtìmọ́lé lọ́nà àìtọ́

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

Ile ẹjọ ECOWAS to wa niluu Abuja ti paṣẹ fun ijọba orilẹ-ede Benin, ko san owo ti iye rẹ to ogun miliọnu owo ile naa fun ajijagbara ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Igboho.

Idajọ yii lo waye lẹyin ti ile ẹjọ naa ni orilẹ-ede ọhun jẹbi bo ṣe ti Igboho mọle, ati pe o tun tẹ ẹtọ ọmọniyan rẹ loju mọlẹ.

Lọjọ Iṣẹgun ni idajọ naa waye, ile ẹjọ ọhun si sọ pe Benin Republic gbọdọ san owo ọhun fun Igboho laarin oṣu mẹra pere, bẹrẹ lati ọjọ to gbe idajọ naa kalẹ.

Awọn adajọ to gbẹ ẹjọ ọhun kalẹ, Gberi-Bé Ouattara, Sengu M. Koroma, ati Ricardo Claúdio Monteiro GONÇALVES, sọ pe orilẹ-ede ọhun gbọdọ san owo naa ni kankan, ko si wa fi ẹri han niwaju oun pe o ti ṣe bẹẹ.

Idajọ yii lo n waye lẹyin ẹjọ ti awọn agbẹjọro Igboho, Tosin Ojaomo, Aderemilekun Omojola Esq., ati Ọmọwe Janet Fashakin Esq. pe ninu oṣu Keji, ọdun 2022.

Wọn pe ẹjọ naa pẹlu ọpọ ọpọ ẹri maa jẹ mi rinṣo tako bi ijọba Benin ṣe fi ṣikun ofin mu Igboho lọjọ kọkanlelogun, oṣu Keje, ọdun 2021.

Ọjọ kẹwaa, oṣe Keji, ọdun 2022 ni awọn agbẹjọro Igboho gbe ẹjọ naa lọ iwaju awọn adajọ.

Gẹgẹ bii ohun to wa ninu iwe ipẹjọ naa, eyii ti BBC foju ri, awọn gbẹjọro rẹ ni ki wọn tu onibara awọn silẹ ni kankan, ki wọn si fun ni iwe irinna ọmọ Naijiria rẹ pada titi ti ile ẹjọ yoo fi gbe idajo rẹ kalẹ.

Bi atimọle Igboho ṣe waye ni Benin

Ti ẹ ko ba gbagbe, ogunjọ, oṣu Keje, ọdun 2021 ni wọn fi ṣikun ofin mu Igboho ati iyawo rẹ, Ropo, niluu Cotonou, lorilẹ-ede Benin, ti wọn si fi si atimọle lẹyin ti ijọba Naijiria ni ki orilẹ-ede naa ṣe bẹẹ.

Ṣaaju ni Igboho ti kọkọ sa asala fun ẹmi rẹ lẹyin ti ikọ ologun ati ọtẹlẹmuyẹ Nigeria, DSS, kọlu ile rẹ to wa lagbegbe Soka, niluu Ibadan, lọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun 2021.

Ki ikọlu DSS naa to waye ni Igboho ti n gbero lati ṣe iwọde ‘Yoruba Nation’ kan niluu Eko, ki awọn ọtẹlẹmuyẹ naa to ṣekupa meji lara awọn eeyan rẹ, ti wọn si fi ṣikun ofin mu awọn mejila.

Ẹsun ti DSS fi ka Igboho

DSS fẹsun kan Igboho pe o n ko ohun ija oloro pamọ, eyii to mu wọn kede rẹ bii ẹni ti wọn n wa.

Amọ lẹyin to lọ si Benin, gbogbo igbiyanju ijọba Naijiria lati da pada wale ni ilana ofin lo ja si pabo.

Ẹwẹ, aipẹ yii ni wọn fi Igboho silẹ ni ahamọ to wa ni Benin lẹyin to ṣe ohun gbogbo to yẹ ko ṣe fun lati gba beeli rẹ.