Iléẹjọ́ ní kí ìjọba Ìpínlẹ̀ Kano san N10m fún títẹ ẹ̀tọ́ Bayero mọ́lẹ̀

Aworan Aminu Ado Bayero

Oríṣun àwòrán, FB/MAIKATANGA

Ile ẹjọ giga to n jokoo niluu Kano, lọjọ Ẹti, ti palaṣẹ fun ijọba ipinlẹ Kano iwipe ki wọn san milọnu mẹwaa Naira owo gba ma binu fun Emir Kẹdogun fun ilu Kano, Aminu Ado Bayero fun bi wọn tẹ ẹtọ rẹ mọlẹ.

Adajọ to gbe idajọ naa kalẹ, Adajọ S.A Amobeda lo sọ eyii lasiko igbẹjọ ti Ado Bayero gbe wa siwaju ile ẹjọ.

Adajọ ṣapejuwe igbesẹ Gomina ipinlẹ Kano, Gomina Abba Yusuf to ni ki awọn agbofinro ma se jẹ ki Bayero kuro ni ile gẹgẹ bii igbesẹ to lodi sofin orilẹede Naijiria.

Awọn olujẹjọ ninu igbẹjọ yii ni, Agbẹro agba nipinlẹ Kano, Ileeṣẹ ọlọpaa, Ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Kọmisọna fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kano, Ajọ agbofinro DSS ati NSCDC, Ileeṣẹ ologun orilẹ, ori omi ati ori ofurufu.

Adajọ ni bi awọn olujẹjọ to jẹ agbofinro se fofin de Bayero, ti wọn dunkoko mọ tumọ si pe wọn ti ẹtọ rẹ mọlẹ gẹgẹ ọmọ orilẹede Naijiria ti ofin ko si fi aye gba bẹ.

Ninu ọrọ rẹ pẹlu awọn akọroyin, agbẹjọro fun Bayero, Mamman Lawan Yusufari ni aṣẹ ti Gomina ipinlẹ Kano, Abba Kabir Yusuf pa pe ki wọn lọ mu Aminu Ado Bayero lai si aṣẹ ile ẹjọ ni ko ba ofin mu.

Bẹẹ ba gba gbe, Aminu Ado Bayero to jẹ Emir karundinlogun ni ilu Kano pe ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ kan ti ile ẹjọ naa gbe kalẹ pe ko gbọdọ pe ara rẹ ni Emir ilu Kano tabi ṣe oju rẹ. Ile ẹjọ naa paṣẹ nigba naa pe ki awọn agbofinro lọ fi panpẹ ọba gbe e ni.

Saaju ni ijọba ipinlẹ Kano da Sanusi Lamido Sanusi pada sipo emir ilu Kano, lẹyin ti o rọ Aminu Ado Bayero loye loni Ọjọbọ.

Igbesẹ yii waye lẹyin ti gomina Kabir Yusuf ipinlẹ Kano buwọ́lù ofin tuntun ọdun 2024 to n ri ipo awọn lọbalọba.

Onidajọ Amobeda Simon to gbọ ẹjọ naa sun igbẹjọ siwaju lẹyin ti o gbọ awijare igun mejeeji.

Agbẹjọro fun olupẹjọ rọ ile ẹjọ naa lati daabo bo ẹtọ Emir Aminu Ado Bayero ki o si maṣe gba ẹnikẹni laaye lati dun mọhurumọhuru mọ ọ.

Agbẹjọro agba fun ijọba ipinlẹ Kano, Mahmud Magaji tako awijare ati ẹbi olujẹjọ naa; to si rọ ile ẹjọ pe ko fi ẹyin ọwọ da a nu.