Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá dóòlà ọmọ ọdún méjì tí wọ́n tìmọ́lé fún ọjọ́ mẹ́ta láì jẹun

Kọmisọna Ọlọpaa Ekiti

Oríṣun àwòrán, Google

Lọjọ aje ọsẹ ni ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti gba awọn ibeji kan lọwọ iya wọn Joy to ti tì wọn mọle fún bii ọjọ mẹta lai fun wọn lonjẹ lagbegbe Igbara Odo nijọba ibilẹ Guusu – Iwoorun ipinlẹ naa.

Gẹgẹ bi awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ṣe sọ pe obinrin ọhun ni oun yoo pa awọn ọmọ naa ti ẹnikẹni ba mu oun ni tulasi lati ṣi ilẹkun.

Wọn ni obinrin naa ni oun n fi ẹhonu han lori bi baba awọn ọmọ naa ṣe pa oun ati awọn ọmọ naa ti lati igba ti oun ti wa ninu oyun ti oun si koju inira gidi.

Kọmisọna ọlọpaa ipinlẹ Ekiti Tunde Mobayo, sọ pe lasiko ti oninure kan ladugbo ranṣẹ pé awọn ọlọpaa ni awọn ikọ oun sare lọ ibi iṣẹlẹ naa ti wọn si fi ọgbọọgbọn SEED doola awọn ọmọ náà.

“Kete ni a ko awọn ọmọ mejeeji lọ ile iwosan fun ayẹwo ati itọju ti iwadii naa si n lọ lọwọ, sugbọn awọn yoo pese aabo to yẹ fun awọn ibeji naa ati iya wọn, Mobayo fidi eyi mulẹ.

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa Sunday Abutu to sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan ni ipinlẹ Ekiti pẹlu akọle: ‘Ọlọpaa Ekiti doola awọn ibeji’ salaye pe awọn gba ipe ijaya pe obinrin kan ti awọn ibeji ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun meji lọ mọle ti ko si fun wọn lonjẹ pẹlu ati pe oun yoo pa wọn ti ẹnikẹni ba mu oun ni tulasi lati ṣilẹkun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Ikọ awọn oniṣẹ pajawiri ni kete ti ipe yii wọle ni wọn gbe igbesẹ lati doola awọn ọmọ mejeeji. Lasiko ifọrọwanilẹnuwo ni obinrin naa ni lati igba ti oun ti wa ninu oyun ni Baba wọn ti lọ si ilu Calabar ni ipinlẹ Cross River ti ko si pada wale mọ lati tọju oun ati awọn ọmọ rẹ.

“Gẹgẹ bi o ṣe sọ, oun ko tilẹ le bọ ẹnu ara Kato wa sọ awọn ọmọ meji naa nitori iru ti oun n ṣe ko lọ dede mọ.

Awọn meji naa ti ọwọ airi itọju wa lara wọn, ko le duro tabi rin ti ẹnikẹni ko ba ran wọn lọwọ nitori airi oúnjẹ jẹ.”

Abutu sọ pe wọn ti ko awọn ọmọ mejeeji naa lọ si ile iwosan loju ẹsẹ fun ayẹwo, fi kun pe iwadii ti bẹrẹ sugbọn ri daju pe aabo to peye wa fun ìyá ati awọn ọmọ naa