Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà dá Akeredolu láre lórí ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo

Jegede ati Akeredolu

Oríṣun àwòrán, others

Ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria ti gbe are fun gomina Rotimi Akeredolu gẹgẹ bi ẹni ti ilu dibo yan si ipo gomina Ondo.

Lẹyin ti idajọ igbimọ to gbọ ẹhonu esi idibo ipinlẹ Ondo to waye loṣu kẹwaa ọdun 2020, ati ile ẹjọ kotẹmilọrun ti kọkọ gbe are fun Akeredolu gẹgẹ bi olubori idibo naa ni Eyitayọ Jẹgẹdẹ to jẹ oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP ninu idibo sipo gomina ipinlẹ naa gbe ẹjọ kotẹmilọrun lọ siwaju ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria.

Ninu adajọ meje to joko gbọ ẹjọ naa mẹrin ninu wọn lo wọgile ẹjọ kotẹmilọrun ti Jẹgẹdẹ pe nitoripe ko fa gomina ipinlẹ Yobe Mai Mala Buni gẹgẹ bi ara awọn to n pe lẹjọ naa.

Adajọ mẹta yooku ninu eyi ti Onidajọ Mary Peter Odili, Ejembi Eko ati Tijjani Abubakar wa gbe idajọ kalẹ pe Buni ko lẹtọ lati duro gẹgẹ bi adele alaga ẹgbẹ oṣelu APC.

Bakan naa ni wọn tun sọ pe gomina ipinlẹ Yobe naa tapa si abala kẹtalelọgọsan iwe ofin orilẹede Naijiria tọdun 1999.

Bakan naa ni mẹrin ninu awọn adajọ meje to gbọ ẹjọ naa tun fọwọ si idajọ igbimọ to gbọ ẹhonu esi idibo ipinlẹ Ondo to waye loṣu kẹwaa ọdun 2020, ati ile ẹjọ kotẹmilọrun lori ẹjọ naa pe ko lẹsẹ nlẹ.