Ilé ẹjọ́ ju akẹ́kọ̀ọ́ 25 láti Fásitì Ajayi Crowther sí ẹ̀wọ̀n lórí ikú akẹẹgbẹ́ wọn

Aworan Oloogbe Timileyin Alex

Oríṣun àwòrán, Others

Ko din ni akẹkọọ mẹẹẹdọgbọn to foju ba ile ẹjọ lara awọn ọmọ ile ẹkọ giga Yunifasiti Ajayi Crowther to wa nipinlẹ Ọyọ l’Ọjọru, ọjọ Karun-un, oṣu Kẹfa, ọdun 2024.

Eyi waye lẹyin ti wọn fi ẹsun kan wọn pe wọn lu akẹkọọ kan Alex Timileyi, pa. Ẹsun ti wọn fi kan Timileyi ni pe o ji foonu.

Ile ẹjọ majisreeti Ibadan ni wọn ti gbọ ẹjọ awọn akẹkọọ mẹẹẹdọgbọn naa.

Kí lohun tó ti ṣẹlẹ̀ kó tóó di ẹjọ́?

Lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2024, ni ọrọ to gbe awọn akẹkọọ yii de kootu waye.

Ibugbe kan ti wọn n pe ni Shepherd Inn, ninu ọgba Yunifasiti Ajayi Crowther ni wọn ni Alex Timileyi t’oun naa jẹ akẹkọọ ti ji foonu.

Iroyin sọ pe awọn akẹkọọ ẹgbẹ rẹ lo fi ẹsun ole jija kan-an.

Wọn bẹrẹ si i fi igi, pankẹrẹ ati waya ina lu u titi to fi ku.

Ibukunoluwa Taiwo, Aarẹ ẹgbẹ akẹkọọ ni Yunifasiti Ajayi Crowther, ṣalaye fun BBC nigba naa pe niṣe ni wọn ti Alex mọ yara kan ti wọn si lu u fun ọpọ wakati ko to o dagbere f’aye.

O ni wọn da omi si i lara pẹlu ki wọn too bẹrẹ si i lu u nitori foonu ti wọn ni awọn ri lọwọ rẹ.

Ọgbẹni Taiwo sọ pe nigba ti iranlọwọ yoo fi de fun Timi, ti awọn fẹẹ gbe e lọ sileewosan, niṣe lo ku kawọn too debẹ.

Bakan naa ni Aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ yii fidi rẹ mulẹ fun BBC lọjọ keji ti awọn akẹkọọ naa foju bale-ẹjọ.

O ni kootu ti paṣẹ ki wọn maa naju lahaamọ titi di ọjọ kẹjọ, oṣu Keje, ọdun 2024.

Yatọ si awọn akẹkọọ mẹẹẹdọgbọn, ile-ẹjọ tun fẹsun kan oṣiṣẹ alaabo, Oladoye Femi, ati ẹni awọn akẹkọọ ma n pe ran niṣẹ, Kehinde Olasusuyi.

Wọn ni wọn kọ lati kegbare tabi doola ọmọkunrin naa nigba ti wọn n fiya jẹ ẹ.

Ile ẹjọ sọ pe ku bojumu bi wọn ṣe kọ lati da awọn akẹkọọ naa lẹkun nigba ti wọn hu iwa ibi ọhun.

Ẹsun igbimọpọ huwa ọdaran ni wọn fi kan awọn mejeeji.

Lẹyin igbẹjọ ni Adajọ paṣẹ ki wọn lọọ fi wọn si ahamọ titi di ọjọ kẹjọ, oṣu Keje, ọdun 2024.

Orukọ awọn olujẹjọ akẹkọọ naa ree bi kootu ṣe gbe e jade:

 • Kumolu Opeyemi Daniel
 • Oluwole Olanshile Thompson
 • Lawal Victor Tomilola
 • Omolakin Oluwatomiwa Anthony
 • Folorunsho Oluwakunmi
 • Bolarinwa Oloruntoyinbo Victor
 • Oladoye Femi Ola
 • Kehinde Olasusuyi Martins
 • Okorie Samuel
 • Mustapha Khalid
 • Mustapha Usman Segun
 • Adeniran Yusuf
 • Oloyede Femi
 • Areye Joseph Aduragbemi
 • Oyelakin Iyanuoluwatomiwa
 • Olalekan Obaloluwa
 • Adejumobi Emmanuel
 • Daudu John Oluwaseun
 • Gana Solomon
 • Moses Abiola
 • Tijani Hammad
 • Omon-Fumen Jenkins
 • Okay-Aroh Gerald
 • Kolawole David
 • Afesojaye Emmanuel