Ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí ṣekúpa èèyàn 35 nínú ìkọlù tuntun

Ológun tó gbé ìbọn lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kò dín ní aráàlú márùndínlógójì tó ti pàdánù ẹ̀mi wọn láàárín ọ̀sẹ̀ kan níbi ìkọlù táwọn agbéṣùmọ̀mí ṣe ní ẹkùn àríwá Kive, orílẹ̀ èdè DR Congo.

Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni ìjà ti máa ń wáyé láàárín àwọn jàǹdùkú tó wà ní ẹkùn yìí lórí ọ̀rọ̀ àlùmọ́nì iẹ̀ bíi wúrà àtàwọn míì.

Ìjà yìí ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn sá kúrò ní ilé wọn.

Ìjọba DR Congo kò ì tíì sọ ohunkóhun lórí ìpànìyàn tuntun yìí àwọn àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé ní ikọ̀ alákatakítí ẹ̀sìn Islam Allied Democratic Forces (ADF) ló wà nídìí ìkọlù náà.

Àwọn tó ṣe ìkọlù náà kojú ìkọlù wọn da àwọn àwọn aráàlú tó wà ní agbègbè ìlú Beni , níbi tí ọ̀pọ̀ ti ṣáájú sá kúrò.

Ìròyìn ní àwọn èèyàn Mamove ni ìkọlù náà ṣọṣẹ́ fún jùlọn níbi tí wọ́n ti ṣọṣẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé, jí ọ̀kadà gbé lọ.

Leon Siviwe, ẹni tó jẹ́ olórí ní Beni ní ó ṣeéṣe kí iye àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn tún lékún bí wọ́n ṣe ń tẹ̀síwájú láti túnbọ̀ ń wá àwọn èèyàn.

Ó sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn AFP News pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti sá kúrò ní ẹkùn náà lọ sí àwọn agbègbè mìíràn tí ààbò wà.

Ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí ADF ni wọ́n dá sílẹ̀ ní ẹkùn ìlà oòrùn Uganda lọ́dún 1990 ti wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbógun ti ààrẹ orílẹ̀ èdè ọ̀hún nígbà náà, Yoweri Museveni fẹ́sùn pé ó ń ni àwọn mùsùlùmí lára.

Nǹkan bíi ọdún mẹ́fà sẹ́yìn báyìí ni ikọ̀ náà ti ń bá àwọn alákatakítí ẹ̀sìn Islam ṣe pọ̀ báyìí.

Láti ọdún 2021 ni iléeṣẹ́ olọgun Uganda àti DR Congo ti ń gbìyànjú láti ṣẹ́gun ikọ̀ ADF àmọ́ ikọ̀ náà kò dẹ́kun láti máa ṣe ìkọlù sáwọn aráàlú.

Bákan náà ni ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí mìíràn M23 tún ti dìde ogun ní ìlà oòrùn DR Congo tí wọ́n sì ti ń gba ìlú mọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò lọ́wọ́.

Àwọn kan ní orílẹ̀ èdè Rwanda ń ti àwọn M23 lẹ́yìn àmọ́ Kigali jiyàn èyí pé irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni.